Ìsìnkú àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pa ní ìpínlẹ̀ Delta yóò wáyé lónìí

Awọn ọmọ ologun ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, NIGERIA ARMY

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti kede pe Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni wọn yoo sinku awọn ologun mẹtadinlogun to padanu ẹmi wọn niluu Okuama, nipinlẹ Delta.

Aago mẹta ọsan ni eto isinku naa yoo waye ni itẹ oku awọn ologun apapọ orilẹ-ede Naijiria.

Isinku yii n waye lẹyin ti rogbodiyan laarin Okuama ati Okoloba, pa awọn ṣọja mẹtadinlogun ọhun.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun to fi aworan awọn ṣọja to doloogbe naa sita loju opo X wọn ṣe ṣalaye, awọn to padanu ẹmi naa ni:

  • Lt Col AH Ali, the Command Officer, 181 Amphibious Battalion, Nigerian Army,
  • Major SD Shafa (N/13976),
  • Major DE Obi (N/14395),
  • Captain U Zakari (N/16348),
  • Staff Sergeant Yahaya Saidu (#3NA/36/2974),
  • Corporal Yahaya Danbaba (1ONA/65/7274),
  • Corporal Kabiru Bashir (11NA/66/9853),
  • Lance Corporal Bulus Haruna (16NA/TS/5844),
  • Lance Coraporal Sole Opeyemi (17NA/760719),
  • Lance Corporal Bello Anas (17NA/76/290),
  • Lance Corporal Hamman Peter (NA/T82653),
  • Lance Corporal Ibrahim Abdullahi (18NA/77/1191),
  • Private Alhaji Isah (17NA/76/6079),
  • Private Clement Francis (19NA/78/0911),
  • Private Abubakar Ali (19NA/78/2162),
  • Private Ibrahim Adamu (19NA/78/6079),
  • Private Adamu Ibrahim (21NA/80/4795)

Kí lohun tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́yin ikú áwọn ológun náà?

Ọga awọn ọmọ ogun Naijiria, Ọgagun Christopher Musa, sọ pe ileeṣẹ ologun mọ awọn eeyan to pa awọn ṣọja mẹtadinlogun naa.

O ni asiko diẹ lo ku tawọn yoo fi ridi iṣẹlẹ yii patapata, nitori awọn n ṣewadii rẹ gidi.

‘’ Ọgagun A.H Ali ti wọn pa ninu awọn eeyan wa yii, fẹẹ fopin sawọn amookunṣika to wa nidii jiji epo rọbi ni Delta ni wọn fi pa a.

‘’Awọn alajangbila yii naa ni nnkan ija pupọ lọwọ, awọn ni wọn lo anfaani ikọlu yẹn lati pa Ọgagun Ali.’’

Bo tilẹ jẹ pe ibẹrubojo ohun ti awọn ologun le ṣe lati gbẹsan ti mu ilu Okuama ati agbegbe rẹ tuka, sibẹ, awọn ṣọja sọ pe kawọn araalu naa maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ.

Wọn ni ti awọn ba tilẹ n mu awọn ọdaran, ẹni ti ko ba jẹ gbii ninu araalu ko ni i ku gbii.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, 2024, ni awọn ologun mẹtadinlogun naa padanu ẹmi wọn lasiko ipẹtu-saawọ ni Okuama, ipinlẹ Delta.