Ìdúnkokoòmọ́ni nípa ẹ̀yà ni iwọ́de Yoruba Nation, IPOB tó wáyé l‘Amẹ́ríkà – Garba Shehu

Awọn eeyan to n se iwọde nibi ipade United Nations

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari feto iroyin, Garba Shehu, ti bu ẹnu atẹ lu iwọde ti awọn ọmọ Naijiria kan ṣe ni orilẹede Amẹrika.

Garba ni iwọde tí ikọ Yoruba Nation ati IPOB to n ja fun ominira ẹya Igbo ṣe lati tako Aarẹ Buhari lasiko to ba awọn adari lagbaye sọrọ ni ipade Ajọ Iṣọkan Agbaye to waye ni New York ko tọna.

Garba Shehu, ninu atẹjade to fi lede ni awọn to ṣe ifẹhọnuhan naa dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria lasiko ti wọn fẹ wọ gbagede ipade Iṣọkan Agbaye, UN naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni idunkokomọni nitori ẹya ni ikọ Yoruba Nation ati IPOB ṣe ni New York, eleyii to ni ko ba ofin mu.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari naa ni, bi o tilẹ jẹ pe wọn ni aṣẹ labẹ ofin lati ṣe ifẹhọnuhan, amọ kii ṣe iwa to bu iyi kun ẹnikẹni lawujọ lati ma a dẹyẹ si eniyan nitori ẹya wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Shehu ni asiko ti aarẹ Buhari n sọrọ lori awọn ipọnju ti orilẹede Naijiria n la kọja, ti o si n rọ awọn adari lagbaye lati dasi iṣoro wọn, ni awọn kan n ṣe ifẹhọnuhan tako aarẹ Buhari ni iwaju Ileeṣẹ Ajọ Iṣọkan agbaye naa.

” Awọn to ṣe ifẹhọnuhan yii ti fihan pe awọn n ṣiṣẹ lodi si orilẹede Naijiria , ti wọn si n da rudurudu silẹ laarin ilu.”

”Bakan naa ni awọn eeyan yii n pa awọn ẹṣọ alaabo, ti wọn si n di awọn araalu lọwọ lati ṣe iṣẹ oojọ wọn nitori wọn fẹ gbe ijọba ara wọn kalẹ ni ọna aitọ”

Gẹgẹbi ọrọ oṣiṣẹ ijọba Buhari naa, o ni aarẹ Buhari n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe ko si ẹni to tẹ ẹtọ ara ilu mọlẹ, ti o si mu ọrọ oju ọjọ to n ṣe segesege lọkunkundun lọna ati mu ki ipese ounjẹ ati idẹra de ba awọn ọmọ Naijiria.

O fikun pe aṣeyọri aarẹ Buhari ko ni abawọn kankan, to fi mọ ṣiṣe iranwọ fun awọn ọmọ Naijiria kọọkan lati di ipo agba mu ni awujọ lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Eleyii fihan pe alaafia ati ifimọṣọkan lawujọ jẹ aarẹ Buhari logun, nitori naa kii ni ifẹ si ohun rudurudu”

”Bakan naa ni aarẹ Buhari n gbiyanju lati ri pe laipẹ awọn eniyan to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria to n gbe ni oke okun ni anfaani lati dibo fun ẹni ti ọkan wọn yan lasiko ti idibo ba n waye lorilẹede Naijiria.”