Ọ̀dọ́ Oduduwa fi oyè Ọmọlúàbí dá Abubakar Malami lọ́lá

Ọ̀dọ́ Oduduwa fi oyè Ọmọlúàbí dá Abubakar Malami lọ́lá

Oríṣun àwòrán, Blueprint

Ẹgbẹ awọn ọdọ ọmọ Oduduwa lagbaye ti fi oye Omoluabi da Agbẹ́jọ̀ro agba ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami lọla lori bo se sisẹ sin ilẹ baba rẹ pẹlu ootọ.

Amugbalẹgbẹ feto iroyin fun minisita naa, Umar Jubrilu Gwandu lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita.

Akinyele Olasunbo, tii se agbẹnusọ fun ẹgbẹ ọdọ Oduduwa lagbaye, wa se apejuwe Malami bii ọmọ Naijiria ti ko mọ ti ara rẹ nikan amọ n ri daju pe isejọba awa ara awa to ba ofin mu fẹsẹmulẹ pẹlu idajọ ododo lai segbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ipa ti minisita feto idajọ naa ko lati gbogun ti iwa ijẹkujẹ lo ti n so eso rere, to si tun ti mu agbega ba igbe aye ati ayanmọ ọmọ Naijiria.

Olasunmbọ wa kan saara si Malami lori bo se n saaju awọn ọlọpọlọ pipe ọmọ Naijiria ni ẹka eto idajọ, eyi to ni o mu ki o tayọ ni gbogbo ọna, to si jẹ awokọse rere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba to n fesi, Abubakar Malami, ẹni ti amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari nidi igbogun ti iwa ọdaran nidi owona, Amofin Abiodun Aikomo soju fun wa fi ẹmi imoore han si ẹgbẹ ọdọ Oduduwa naa.

O wa mẹnuba ojuse pataki ẹgbẹ ajafẹtọẹni nidi aseyọri awọn eto idagbasoke eyi ti yoo ri daju pe agbega bawọn agbegbe igberiko wa.