Bí àwọn aráàlú ṣe dóòlà Farida Sobowale tó fẹ́ kó sínú odò 3rd Mainland Bridge

Farida Sobowale

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajumọ kan ni ilu Eko, Arabinrin Farida Sobowale ti fidio gba ori ayélujára níbi tí àwọn eeyan ti n bẹ ẹ ko ma ko sinu odo ni ẹnu ti n kun lori rẹ.

Nínú fidio to gba ori ayelujara kan ọhun la ti rii ti awọn kan to n kọja lọ n doola rẹ lapa ibi kan lori afara odo Third Mainland nigba to n gbiyanju lati fo sinu odo Ìpínlẹ̀ Eko yii lati pa ara rẹ ni Ọjọbọ.

Iroyin ni arábìnrin yii to jẹ oludasilẹ ati Ọga Ileeṣẹ awọn nkan aṣaraloge ni Ìpínlẹ̀ Eko dede wa ọkọ lọ si ori afara Third Mainland Bridge o si dede paaki ọkọ, o bọ silẹ o si fẹ bẹ sinu omi ko to di pe awọn kan da a duro.

Fidio naa tun ṣafihan oníṣòwò yii ni ipo ibanujẹ tohun ti omije loju ti awọn onworan kan si yí i ka lati ba a kẹ́dùn.

Aworan Farida

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bo tilẹ̀ jẹ́ wipe idi to fi fẹ ko sodo ko tii ni aridaju ṣùgbọ́n ọpọlọpọ gbọ́yìísọyìí lo ti jade wipe nitori ìṣòro to koju ninu igbeyawo rẹ ni.

Iṣẹlẹ ti Farida yii ni eyi to ṣẹ tun sẹlẹ ninu ọpọlọpọ iṣẹlẹ awọn eeyan lori afara omi Third Mainland àtàwọn afara odo mii kaakiri ilu Eko eyi to ti fa ọpọ idamu ni lemọ lemọ bo tilẹ̀ jẹ́ pe iwa gbigba ẹ̀mí ara ẹni lodi si ofin orileede Naijiria.

Ki ni iwe ofin Naijiria sọ?

Gẹgẹ bi abala 327 ẹ̀ka iwe ofin Naijiria to ni ṣe pẹlu iwa ọ̀daràn, o sọ wípé, „ẹnikẹni ti o ba gbiyanju lati gba ẹ̀mí ara rẹ jẹbi o si yẹ ko lọ si ẹ̀wọ̀n ọdun kan.

Ni ọ̀sẹ̀ to kọja ni wọn ṣi gbe oku arakunrin kan jade ninu odo Lekki-Ikoyi Link Bridge.

Wọn fura pe arakunrin naa ku lẹyin to ti pa ara rẹ lẹyin ọjọ meji gẹgẹ bi atẹjade àjọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Èkó, LASEMA ṣe sọ ọ.