Ó wù mí láti bímọ oyè fún Ooni, ẹ̀yin alálẹ̀, ẹ fún mi ní ìbejì – Ashley Ogunwusi

Olori Asyley ati Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Queen Ashley Afolashade Ogunwusi/Instagram

Yoruba ni ẹnu ẹni la fi n pe Temidire, ohun ta ba si fi ẹnu wa sọ si ara wa, o di dandan ko ri bẹẹ.

Eyi lo mu ki Olori Ashley Afolashade Ogunwusi, tii se ọkan lara awọn iyawo Ooni ti ilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, se n bẹ awọn alalẹ lọwẹ pe ki wọn fun oun ni ibeji ti yoo jẹ ọmọ oye.

O ni nitori pe o wu oun lati bi ibeji ni aafin Ọba Adeyeye Ogunwusi.

Olori Ogunwusi rawọ ẹbẹ yii ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan, eyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ.

Ninu fidio naa ni Olori Ashley ti n ba ipejọpọ awọn agbaagba kan lọkunrin ati lobinrin sọrọ, to si n se adura kikankikan.

Olori naa, to wọ asọ ibilẹ to jẹ funfun pẹlu ọja saki si ejika rẹ, lo joko sori aga kan ni gbagede igbalejo Ooni, to wa ninu aafin Ile Ife.

Bi Olori Ashley si se n se adura naa, lawọn abẹsẹ, alejo ati iransẹ ninu aafin naa n se asẹ Edumare.

Olori Ashley Ogunwusi nibi to ti n gbadura laarin ero

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Olori Ashley Ka ọmọ marun fun Ooni Ogunwusi lasiko to n se adura

Ninu fidio ọhun, lasiko to n gbadura naa, ni orogun rẹ, Ronke Ademiluyi ti joko sẹgbẹ , to si n gbadura fun ọkọ wọn.

Olori Ashyley ni Ooni Ogunwusi, tii se Arole Oodua ni baba Adeola, Baba Adewamiwa, baba Fadesola, baba Tadenikawo ati baba Adeife.

“Mo dupẹ lọwọ baba, ti mo ba ni ki n maa ki wọn lọ, a ni kuro nibi yii nitori wọn to bẹẹ, wọn si ju bẹẹ lọ.

Mo wa gbadura pe mimi kankan ko ni mi i mọ lode aye, yoo gbo, yoo tọ, ti yoo si fi erigi jobi.

Gbogbo olori ni yoo dijọ maa ko ọmọ lubọ laafin, a finu soyun, a fi ẹyin gbe ọmọ pọn.”