Bí ológun bá ṣèjọba ní Niger, yóò lẹ́yìn f’órílẹ̀èdè àgbáyé, Ààrẹ Niger ké sí Amẹ́ríkà

Aworan Mohammed Bazoum

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Niger to wa ni ahamọ awọn ologun to ditẹgbajọba, Mohamed Bazoum ti kesi orilẹede Amẹrika ati awọn orilẹede agbaye miiran lati pese iranlọwọ eyi ti yoo da ijọba awarawa pada lẹyin iditẹgbajọba to waye lọsẹ to kọja.

Atẹjisẹ Bazoum lo wa ni oju iwe iroyin Washington Post, to si sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹlẹwọn to n kọ atẹjisẹ.

Rogbodiyan bẹrẹ lorilẹede naa lati igba ti ijọba ologun ti gba ijọba.

Lọjọbọ, awọn olori ikọ ijọba ologun naa kede pe awọn ko ni ibasepọ kankan pẹlu orilẹede France, Amẹrika, Naijiria ati Togo.

Ninu atẹjade ti wọn ka sita lori ẹrọ mohunmaworan, ijọba ologun orilẹede Niger naa lkesi awọn asoju wọn lawọn orilẹede ti wọn darukọ naa pe awọn ko ran wọn ni isẹ mọ.

Aworan awọn eeyan to n wọ asia Russia

Oríṣun àwòrán, EPA

Bazoum ninu atẹjisẹ ni ti iditẹgbajọba naa ba fi le ri di mulẹ lorilẹede Niger, atunbọ rẹ ko ni san awọn ọmọ orilẹede naa ati gbogbo agbaye ni apapọ.

“Ijọba awarawa nikan lo le tan isoro isẹ, ti yoo si bọwọ fun ofin ilẹ wa ati yoo se iranlọwọ fun lori igbogun ti iwa igbesunami.

“Awọn ọmọ orilẹede Niger ko ni gbagbe gbogbo iranlọwọ ti ẹ ba pese fun wọn lasiko yii.”

Bazoum wa se ikilọ pe awọn olori awọn ologun ti kede ibasepọ wọn pẹlu ikọ ologun Wagner lorilẹede Russia, ti wọn si wọle si orilẹede Niger.

“Gbogbo awọn alatilẹyin iditẹgbajọba naa lo ti n pariwo sita ni ede Russia, ti wọn si n gbe asia Russia kiri gbogbo agbegbe wa.”

Lọjọbọ, ogunlọgọ awọn eeyan lo tu sita ni Niamey, ti wọn si n se iwọde alaafia lati se atilẹyin fun iditẹgbajọba naa, ti wọn si nnka abuku si awọn orilẹede adulawọ ti wọn pasẹ fun wọn lori bi wọn yoo se ijọba ni Niger.

Ṣé lóòótọ́ ni pé Nàìjíríà ti ń kó ọmọogun jọ láti kọlu Niger?

Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà àti Ọ̀gágun Tchiani

Oríṣun àwòrán, RTN/GETTY IMAGES

Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti bọ́ síta láti wá sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan tó gba orí ayélujára pé àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà ti ń mórílé orílẹ̀ èdè Niger látàrí ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé níbẹ̀.

Iléeṣẹ́ ológun ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà nítorí kò sí ẹnikẹ́ni tó ti pa àwọn láṣẹ láti gba orílẹ̀ èdè Niger lọ láti lọ fipá mú àwọn ológun tó gba ìjọba níbẹ̀.

Ní ọjọ́rú ni ìròyìn gba orí ayélujára pé àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà ti gbáradì láti lọ kojú àwọn ológun tó fipá gba ìjọba ní Niger.

Ìròyìn náà tó gba orí Twitter ní àwọn ọmọ ogun ti ń kóra jọ sí ìpínlẹ̀ Sokoto láti lọ ṣe ìkọlù sáwọn ológun Niger àmọ́ iléeṣẹ́ ológun ní irọ́ ni ìròyìn náà.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Keje ọdún 2023 ni àwọn ológun fipá gba ìjọba ní Niger èyí tí wọ́n kéde lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, tí wọ́n sì ti gbogbo ẹnu ibodè tó wọ orílẹ̀ èdè náà pa.

Ọ̀gágun Aabdourahmane Tchiani kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí orílẹ̀ èdè Niger lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba ọ̀hún.

Àtẹ̀jáde kan tí adelé adarí iléeṣẹ́ ológun, Ọ̀gágun Tukur Gusau fi léde lọ́jọ́rú ní àwọn ṣì ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ àti pé àwọn kò ìtíì rí àṣẹ gbà láti gbé ìgbésẹ̀ tàbí bẹ̀rẹ̀ ogun ní Niger.

Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Niger tó gbe àsíá dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹ́yìn tí àwọn ológun gba ìjọba tán ní Niger, àwọn olórí orílẹ̀ èdè ti àjọ ECOWAS ṣèpàdé ní Abuja níbi tí wọ́n ti fẹnukò lórí àwọn ìgbésẹ̀ kan láti fòfin de àwọn ológun tó gba ìjọba náà.

Lára àwọn ìfenukò wọn ni pé wọ́n fún àwọn ológun náà ní ọjọ́ méje láti dá ìjọba padà fún ààrẹ Bazoum.

Bákan náà ni ECOWAS tún pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tó múlé ti Niger ti ẹnubodè wọn pé mọ́ wọn àti pé kò gbọdọ̀ sí lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ òfurufú láàárín wọn àti Niger.

Àmọ́ àwọn ológun Niger bu ẹnu àtẹ́ lu gbogbo òfin náà, tí ọ̀gágun Tchiani sì ní òfin tí wọ́n fi de àwọn kò dára tó àti pé àwọn kò ní gbé ìjọba lé Bazoum lọ́wọ́ rárá.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn orílẹ̀ èdè bíi Burkina Faso àti Mali tó jẹ́ alámùúlétì Niger náà ti ń ṣèkìlọ̀ pé tí àwọn ológun bá filè wọ Niger, ó túms sí pé ogun yóò bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀ èdè náà.

ECOWAS náà ti wá fohùn léde pé kíkó àwọn ọmọ ogun lọ sí orílẹ̀ èdè Niger kìí ṣe nǹkan tí àwọn fẹ́ ṣe báyìí àti pé ó dìgbà tí kò bá sí ohun tí àwọn le ṣe mọ́ ni àwọn tó le gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

ECOWAS ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lórí ogun tó wáyé ní Niger láti ọjọ́rú ọjọ́ Kejì oṣù Kẹjọ tí ìpàdé náà yóò sì wá sí òpin lọ́jọ́ Ẹtì.

Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè UK tó ń kúrò ní Niger

Oríṣun àwòrán, Reuters

Níbi ìpàdé náà, kò sí asojú kankan láti Mali, Niger, Guinea Bissau, Burkina Faso àti Guinea nítorí ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé láwọn orílẹ̀ èdè náà èyí tó jẹ́ kí ECOWAS yọ wọ́n kúrò nínú ọmọ ẹgbẹ́ wọn.

Àwọn ọmọ ogun láti Ghana, Nàìjíríà, Benin, Togo, Sierra Leone, Senegal, Liberia, The Gambia, Cote D’Ivoire àti Cape Verde nìkan ló wà níbi ìpàdé náà.

Lára ìfẹnukò ECOWAS láti mójútó ìfipágbàjọba tó wáyé ní Niger, wọ́n rán ikọ̀ kan èyí tí olórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí Ọ̀gágun Abdulsalami Abubakar ṣaájú rẹ̀ lọ sí Niamey fún ìjíròrò láti gba àláfíà láàyè.

Ọ̀pọ̀ àwọn àwọn orílẹ̀ èdè ló ti ń kó àwọn ènìyàn wọn kúrò ní Niger nítorí wọn kò mọ ohun tó le tẹ̀yìn ìfipágbàjọba náà wáyé.

Orílẹ̀ èdè UK ti kó gbogbo àwọn ènìyàn wọn, tí Amẹ́ríkà náà sì ti káde láti kó àwọn ènìyàn rẹ̀ ní iléeṣẹ́ US tó wà ní Niger kúrò.