Ìjọba ti ilé ọmọ aláìní ìyá pa fẹ́sùn títa àwọn ọmọ

Ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow of God tí wọ́n tì pa

Oríṣun àwòrán, Anambra Ministry of Women and Social Welfare

Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ti ti ilé àwọn ọmọ aláìní ìyá kan, Arrow of God Community Children’s Home tó wà ní Nkwelle Ezunaka ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyi ìpínlẹ̀ náà pa.

Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ àwọn obìnrin àti ìgbáyégbádùn àwùjọ ní ìpínlẹ̀ Anambra, Ify Obinabo ló fi ìkéde náà síta tó sì tún ní àwọn ti gba ìwé àṣẹ tí wọ́n fún iléeṣẹ́ náà.

Ohun tó fa ìgbésẹ̀ ìjọba Anambra yìí kò ṣẹ̀yìn ìròyìn kan tí iléeṣẹ́ Foundation for Investigastive Journalism gbé jáde níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan ilé ọmọ aláìní ìyá náà pé wọ́n ń ta ọmọ lọ́nà àìtọ́.

Ìròyìn náà ní iléeṣẹ́ ìjọba tó ń rí sọ́rọ̀ àwọn obìrin àti ìgbáyégbádùn àwùjọ náà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àìtọ́ tí ilé ọmọ aláìní ìyá náà ń ṣe.

Kọmíṣọ́nà ní kété tí àwọn rí ìròyìn náà ni àwọn ránṣẹ́ pé olùdarí ilé ọmọ aláìní ìyá ọ̀hún Deborah Ogo ṣùgbọ́n tó kọ̀ tí kò jẹ́ ìpè àwọn.

Obinabo ní àìwá sí iléeṣẹ́ àwọn wà lára ìdí tí àwọn pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò fi ti ilé ọmọ aláìní ìyá náà pa.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti ilé ọmọ aláìní ìyá náà, Obinabo ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ìgbáyégbádùn àwùjọ kò mọ nǹkankan nípa bí wọ́n ṣe ta ọmọ.

Ó ṣàlàyé pé lára àwọn nǹkan tó fojú hàn tó sì wẹ iléeṣẹ́ àwọn mọ́ ni pé àwọn mẹ́ta láti iléeṣẹ́ òun ló yẹ kí ó buwọ́lu ìwé tí ènìyàn bá fẹ́ gba ọmọ sọ́dọ̀ àmọ́ kò sí ìbuwọ́lù ẹnìkankan nínú àwọn níbẹ̀.

Ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow of God tí wọ́n tì pa

Oríṣun àwòrán, Anambra Ministry of Women and Social Welfare

Ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow of God tí wọ́n tì pa

Oríṣun àwòrán, Anambra Ministry of Women and Social Welfare

Bákan náà ló ní láti ìgbà tí òun ti di Kọmíṣọ́nà, ilé ẹjọ́ májísíréètì tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ àti àwọn ẹ̀sùn ìfìyàjẹni ti ìlú Awka ni àwọn ti ń gba ìwé àṣẹ dípò ilé ẹjọ́ Nnewi èyí tó wà nínú ìròyìn náà.

Ó ní èyí rí bẹ́ẹ̀ láti le ṣe àmójútó ọmọ tí àwọn bá fún alágbàtọ́.

Obinabo wá ṣèkìlọ̀ fún àwọn ilé ọmọ aláìní ìyá mìíràn tó wà ní ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n bá ń ṣe irú owó títa ọmọ tàbí gbé ọmọ fún alágbàtọ́ lọ́nà àìtọ́ pé kí wọ́n lọ jáwọ́ tàbí kí wọ́n fojú winá òfin.

Ó ní ìjọba kò ní kó àárẹ̀ ọkàn láti ṣe àwárí àwọn ilé ọmọ aláìní ìyá tó bá ń irú iṣẹ́ láabi báyìí.

Ó tún rọ àwọn òbí tó bá fẹ́ gba ọmọ tọ́ láti fi ohunkóhun tí wọ́n bá rí tó lòdì sí òfin tó ilé iṣẹ́ àwọn létí nígbà tí wọ́n bá dé ilé ọmọ aláìní ìyá.

Ó fi kun pé àwọn ọmọ ogun ni àwọn gbé kúrò ní ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow of God tó fi ma ọmọ ìkọkọ kan.

Ó ní àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún kan sí ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni àwọn náà èyí tí ọkùnrin wọn jẹ́ mẹ́wàá tí àwọn obìnrin sì jẹ́ mẹ́sàn-án pẹ̀lú ìkókó kan.

Ó ní àwọn ọmọ náà ló ti wà lábẹ́ ìtọ́jú ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra títí àwọn máa fi wá àwọn ẹbí wọn kàn.

Akọ̀ròyìn ra ọmọ ní N2m

Ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tì pa

Oríṣun àwòrán, FIJ

Ní ọjọ́bọ̀ ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹjọ ni iléeṣẹ́ ìròyìn Foundation for Investigative Journalism gbé ìròyìn kan jáde pé ilé ọmọ aláìní ìyá kan ń ta ọmọ lọ́nà àìtọ́.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà tó ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé bí ó ṣe gbà á ní oṣù makàndínlógún láti fìdìí ìwádìí náà múlẹ̀ àti bó ṣe pàpà ra ọmọ oṣù mẹ́fà ní mílíọ̀nù méjì náírà ní ilé ọmọ aláìní ìyá Arrow of God ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Soyombo ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ra fóònù fún ìyá tó ni ilé ọmọ aláìní ìyá ọ̀hún, Rev. Deborah Ogo láti lè gbà láti ta ọmọ fún wọn.

Lẹ́yìn-ò-rẹ̀yìn Soyombo ní àwọn gba ọmọ oṣù mẹ́fà láì tẹ̀lé òfin àti ìlànà tó yẹ èyí tó lòdì sí òfin Nàìjíríà.

Ó ní láti ìpínlẹ̀ Eko ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ òwò náà kí ilé ọmọ aláìní ìyá náà tó ní kí àwọn wá gba ọmọ ní ẹ̀ka rẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Aanmbra.

Èyí lo mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ti ilé ọmọ aláìní ìyá náà àmọ́ tí olùdásílẹ̀ rẹ̀ Rev. Deborah Ogo àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sì ti ná pápá bora.

Bákan náà ni ẹ̀ka ilé ọmọ aláìní ìyá náà tó wà ní agbègbè Ajah ní ìpínlẹ̀ Eko ti jẹ́ títí pa látọwọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fẹ́sùn lílòdì sí òfin.