Ọkọ mi pa ọmọ wa mẹ́ta, o kó òkú wọn sínú fírísà – Milliscent Amadikwa

Milliscent Amadikwa

Obinrin kan ti fẹsun kan ọkọ rẹ pe o pa ọmọ wọn mẹta, o si ko oku wọn sinu ẹrọ amomi tutu firiji ninu ile wọn.

Obinrin ọhun, Milliscent Amadikwa fẹsun naa kan ọkọ rẹ, Ifeanyi Amadikwa niluu Emene, ni ipinlẹ Enugu lẹyin to ri awọn ọmọ naa ninu firisa ile wọn.

O ṣalaye nigba ti BBC kan si ile wọn pe ọkọ rẹ ọhun gan lo ṣi firiji to si ni inu rẹ ni awọn ọmọ wa.

Orukọ awọn ọmọ naa ni, Chimdalu, to jẹ ọmọ ọdun mọkanla, Amara, to jẹ ọmọ ọdun mẹjọ ati Ebube, to jẹ ọmọ ọdun marun un.

Ṣaaju ni tọkọtaya naa ti kọkọ n wa awọn ọmọ ọhun lọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii ki wọn to ri awọn naa ninu firisa.

Obinrin ọhun ṣalaye fun akọroyin BBC to ṣabẹwo sile wọn pe lalẹ ọjọ yii kan naa ni ọkọ oun ṣi firiji ile wọn, to si sọ fu oun pe inu firisa naa ni awọn ọmọ ọhun wa.

O ni “nigba to ṣi firisa lalẹ lalẹ ọjọ ti an sọ yii lo sọ pe wo awọn ọmọ ti a n wa ni wọn korajọ sinu firiji.”

“Ni kete ti mo foju ganni awọn ọmọ naa ni mo ke gbajare si gbogbo adugbo ki wọn gba mi.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹyin eyii ni wọn ko awọn ọmọ naa lọ sile iwosan nibi ti dokita ti sọ pe wọn ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ni bayii, obinrin naa ti wa n fi ẹsun kan ọkọ rẹ pe ṣe ni o mọọmọ pa awọn ọmọ oun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹnu awọn ọmọ mẹtẹta naa dudu bii pe wọn ti mu majele, ọkọ oun si sọ fun oun pe oun lo fun wọn ni tea mu.

Milliscent fi kun un pe oun funra si ọkọ oun nitori o ti pẹ to ti maa n dun mọhuru-mọhuru mọ oun ni gbogbo igba ti wọn ba ni ede aiyede ninu ile, ati pe omi kankan ko bọ loju rẹ lẹyin to gbọ nipa iku awọn ọmọ mẹtẹta naa.

Obinrin naa pari ọrọ rẹ pe oun ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, wọn si ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati mo ohun to ṣekupa awọn ọmọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ