Fídíò, Àgbéyẹ̀wò aáwọ̀ àárín Russia àti Ukraine- Oyeniyi Bukola tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ olùkọ́ nípa ìtàn ilẹ̀ Yúròòpù, Duration 9,34

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ukraine and Russia History: Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàrín Russia àti Ukraine- Oyeniyi Adeyemi

Bi omo ko ba ba itan, o di dandan ko ba aroba to jẹ́ baba itan ni ọ̀rọ̀ Ukraine ati Russia.

Eyi lo jẹ́ ki BBC Yoruba wa itan laasigbo aarin Ukraine ati Russia lo siwaju awọn akọsẹ́mọ́sẹ́ ninu itan lọ.

Ojogbon Oyeniyi Bukola Adeyemi ni Fasiti Missouri ni orile-ede America ti so itan ija Russia ati Ukraine.

Awon koko mii wo ni Oyeniyi Adeyemi tun menuba lori ọ̀rọ̀ ipa ikolu Russia si Ukraine?

Akosemose ninu itan ilẹ̀ Yuroopu yii menuba awon ipa ti laasigbo yii n ni lori awon orile-ede mii bii Naijiria pe:

Ìdá mẹ́rìndínlógójì ‘wheat’ tá ń jẹ ní Nàìjíríà ló ń wá láti Ukraine tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ tí à ń lo sì jẹ́ pípèsè ní Russia.

Ukraine ati Russia

Kini awon nkan ti Ojogbon Oyeniyi tun sọ̀?

Ojogbon Oyeniyi Bukola Adeyemi to kawe gboye ẹ̀kọ́ lori History and International Relations lati ipele ẹ̀kọ́ akoko lati Fasiti akọ́kọ́ ni Naijiria, iyen University of Ibadan nibi ti sanmọnti gbe dun ilẹ̀ salaye sii lori ipa ti laasibo yii n ko.

Àgbéyẹ̀wò aáwọ̀ àárín Russia àti Ukraine: Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Ipa ti àwọn orílẹ̀ èdè méjéjèjì ń kó lórí ètò àgbáyé kò kéré rárá ni awọn orile-ede to yi won ka ati ni agbaye lapapo

Ki tun ni awon alaye mii ti Oyeniyi Fasiti Amerika tun so?

Oyeniyi ni pe: Ìdá mẹ́rìndínlógójì wheat tá ń jẹ ní Nàìjíríà ló ń wá láti Ukraine tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ tí à ń lo sì jẹ́ pípèsè ní Russia

Bakan naa ni Olukọ́ awon akekoo ninu itan ati ajosepo orileede yii tun menuba ibi to le jasi fun awon orile-ede mejeeji bi itan se fihan

Oyeniyi Bukola Adeyemi