Ọmọ ọdún 15 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lòpọ̀ fojú balé ẹjọ́ l’Eko

Ọmọ ọdun marundinlogun kan ti kawọ pọn rojọ niwaju adajọ Majistreeti kan niluu Eko lori ẹsun pe o fọwọ kan ọmọ ọdun mẹjọ lọna ti ko tọ.

Ileeṣe ọlọpaa gbe ọmọ naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibalopọ lọna aitọ.

Ọlọpaa to n ṣe ẹjọ ọhun, ASP Akpan Nko ṣalaye fun ile ẹjọ naa pe afurasi wu iwa ọdanran naa lọjọ kẹsan an, oṣu Keji, ọdun 2022 ni adugbo Oladejo, ni Araromi, Badagry, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, iwa ti afurasi na wu lodi si abala 137, 170 ati 261 ninu iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.

Adajọ ile ẹjọ naa, Patrick Adekomiya, gba beeli afurasi naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ati oniduro meji.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ki igbẹjọ naa le bẹrẹ ni pẹrẹwu.