Ilé ẹjọ́ fi Rahman Adedoyin pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe bẹ̀rẹ̀ l’Osun

Timothy Adegoke

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ti fi Rahman Adedoyin atawọn mẹfa mii si ahamọ lori iku Timothy Adegoke.

Lẹyin ti Ile ise ọlọpaa fẹsun kan awọn afurasi naa pe wọn lọwọ ninu iku Timothy Adegoke to je akẹkọọ ni OAU.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa fẹsun ipaniyan kan Oludari Ile itura Hilltop Hotel ati awọn afurasi meje miran, awọn afurasi naa ti sọ fun Ile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun kankan.

Ile ẹjọ giga ipinle Osun ti joko lonii lati gbọ ẹjọ iku Timothy Adegoke, akeko Obafemi Awolowo University to jade laye lẹyin to sun Ile itura Hilton ni Ile Ife.

Ara ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi naa ni gbigbe oku Timothy sin leyin iku rẹ ati awọn ẹsun miran.

Awọn afurasi naa ni wọn sọ fun Ile ejọ pe awọn ko jẹbi ẹsun kankan.

Agbẹjọro fun awọn afurasi naa, Kunle Adegoke ati K. Eleje pe fun anfaani fun awọn afurasi lati ma jẹjọ lati Ile wọn ṣugbọn awọn olupẹjọ fariga si ipe naa.

Adajọ Adepele Ojo wa sun igbẹjọ naa si ọla ode lẹyin ti awọn afurasi naa mẹnu ba ọrọ eto Ilera awon.

Ile ẹjọ ti wa fi awọn afurasi naa si ahamọ ọgba ẹwọn niluu Ilesha.

Ki lo ti sẹyin?

Adájọ́ gbé ìgbésẹ̀ lẹ́yìn tí awuyewuye wáyé láàrin ẹbí Timothy àti Adedoyin ní Osogbo lónìí

Timothy Adegoke àti Ramon Adedoyin

Timothy Adegoke: Ile ejo sun igbẹ́jọ́ si ola, ojọ́ kerin, osù keta, ọdún 2022

Ile ejo giga High Court ti Oke Fia ni ilu Osogbo ni ipinle Osun to n gbo ejo lori iku to pa Oloogbe Timothy Adegoke ti sun ipejo si ola leyin ti awon afurasi so fun Ile ejo naa pe eto Ilera won ko ja musemuse.

Awon afurasi mefa naa pelu Oloye Rahmon Adedoyin ni wọ́n fesun kan pe wọ́n lọ́wọ́ ninu iku Timothy Adegoke.

Kini o sele nile ejọ́ lonii?

Adajo Adepele Ojo jẹ́ adajọ́ lori ejo naa si so pe ki awon afurasi naa si wa ni atimole titi ti igbejo naa yoo fi tesiwaju di ola fun Itesiwaju.

Ni afikun ni gbọ́nmi si omi ko too sele larin molebi Rahmon Adedoyin ati Molebi Timothy Adegoke ni Ile ejo naa ni Oke Fia ni Osogbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Egbon Oloogbe Timothy, iyen Gbade Adegoke fi esun kan awon Ile ise olopaa pe ki won fi oju won awon afurasi naa fun awon akoroyin hab sita.

O ni ko dara to bi lọ́pàá se n daabo bo awọn ika afurasi naa ninu ọ̀rọ̀ re

Ilé ẹjọ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ Ramon Adedoyin àti àwọn mẹ́fa mìíràn lónìí ní Osogbo

Timothy Adegoke àti Ramon Adedoyin

Kini o koko sele nile ejọ́ lonii?

Lọ́wọ́lọ́wọ́ bi a se n sọ̀rọ̀ yii ni igbejọ ikú oloogbe Timothy Adegoke n lo lọ́wọ́ nile ẹjọ́ giga ti Oke Fia nilu Osogbo.

Ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke àti Rahmon Adedoyin ti bẹ̀rẹ̀ báyìí nílé ẹjọ́ gíga Osogbo

Ilu Osogbo jẹ́ olu ilu ipinle Osun ni iwo ooru guusu Naijiria.

Adajo Adepele Ojo ni yoo se idajo ẹ̀jọ́ naa nibi ti wọ́n ti fesun kan Rahmon Adedoyin to nile itura naa ati awọn mẹ́fa mii.

Ile ìtura Hilton yii wa ni ilu Ilé Ifẹ̀ ni ipinle Osun nibe naa ni àwọn afurasí mẹ́fa mìíràn tó ń kojú ẹ̀sùn níní ọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ilé Ifẹ̀ naa ti jade.

Òní lòníi ń jẹ́ lórí ẹjọ̀ Timothy Adegoke àti Ramon Adedoyin pẹ̀lú àwọn mẹ́fà mii tí wọ́n fẹ̀sùn kàn Osun

Ìgbẹ́jọ́ Ramon Adedoyin tó ni ile ìtura Hilton, Ilé Ifẹ̀ àti àwọn afurasí mẹ́fa mìíràn tó ń kojú ẹ̀sùn níní ọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ilé Ifẹ̀ tó kú sí ilé ìtura náà ń tẹ̀síwájú lónìí.

Ẹ̀gbọ́n olóògbé, Gbade Adegoke fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fun BBC pé ní ìpínlẹ̀ Osun tó jẹ́ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lọ́dún tó kọjá ni ìgbẹ́jọ́ yóò ti máa tẹ̀síwájú lónìí.

Timothy Adegoke àti Ramon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, others

Ilé ẹjọ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ Ramon Adedoyin àti àwọn mẹ́fa mìíràn lónìí ní Osogbo

Gbade ni aago mẹ́sàn-án ní àárọ̀ yìí ni ìgbẹ́jọ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó wà ní Osogbo.

Kini o bi igbejọ̀ naa leyin iku Timothy Adegoke?

Ramon Adedoyin ló ń kojú ẹ̀sùn pé ó sin òkú Timothy Adegoke lọ́nà àìtọ́.

Nigba tí àwọn mẹ́fa yóòkù Adedeji Adesola, Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderogba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem àti Adebayo Kunle ni wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìlẹ̀dí-àpò-pọ̀ ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wa ní Abuja tẹ́lẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Agbejoro won Femi Falana ti se sẹ́yin?

Agbẹjọ́rò mọ̀lẹ́bí Timothy Adegoke, Femi Falana kọ̀wé ráńṣẹ́ sí ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀ dè yìí, Usman Baba láti dá ẹjọ́ náà padà sí ìpínlẹ̀ Osun nítorí níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìgbẹ́jọ́ náà yóò máa tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Osun lónìí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bákan náà ló fi kun pé òun kò mọ̀ bóyá Ramon Adedoyin àti àwọn afurasí yóòkù tí gúnlẹ̀ sí Osun lálẹ́ àná láti kojú ìgbẹ́jọ́ wọn lónìí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ