Àrá sán pa ọkùnrin méjì ní Kwara

Aworan Ara

Oríṣun àwòrán, Google

Eeyan meji kan lo ti ri iku ojiji re lẹyin ti oju ọjọ daru tí ara si san pa ọkunrin Hausa kan ati olubara rẹ ni agbegbe Ẹyẹnkọrin ni ijọba ibilẹ Asa nipinlẹ Kwara.

Iṣẹlẹ ọhun waye ni orita Onigbegiri ni Ẹyẹnkọrin lọjọbọ ọsẹ yii lẹyin ti ojo rọ.

Osojumikoro, Mojeeb Onigbegiri to ba awọn akọroyin sọrọ salaye pe ọkunrin Hausa yii n ‘Tea’ fun ọkunrin keji, lasiko ti ara ọhun san to si gba ẹmi awọn mejeeji ni bi ago mẹfa abọ ọjọ naa.

Ohun to fa bí ara naa se san ni a ko le sọ, sugbọn awọn olugbe agbegbe naa ti kesi ìjọba ìpinlẹ ati Ileeṣẹ Ọlọpaa lati wa gbe oku awọn eeyan kuro.

Alukoro fun Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara, SP Okasanmi Ajayi ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Otitọ ni iṣẹlẹ to waye ni agbegbe Onigbegiri ni Ẹyẹnkọrin níbi ti ara ti san pa eeyan meji lẹyin ti ojo rọ.

O ni oku Ọkunrin Hausa ni awọn mọlẹbi rẹ tí wa gbe lati lọ sìn, ti oku ẹnikeji si wa ni akata ileeṣẹ Ọlọpaa nitori awọn mọlẹbi rẹ ni awọn yoo gbe awọn igbesẹ kan lori oku naa ki awọn to le sin.