Ẹ wo ibi tí ìjà alágbára méjì tó ń darí Kano yọrí sí; Ànfàní wo ni gómìnà tuntun yìí yóò mú wá?

Kwankwaso, Kabir ati Ganduje

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ija ta ni yoo gba agbara idari ipinlẹ Kano laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati NNPP ti pari bayii pẹlu bi ajọ eleto ilera, INEC ṣe kede pe Yusuf Kabir ti ẹgbẹ oṣelu NNPP lo jawe olubori gẹgẹ bi gomina tuntun.

Kabir ni iye ibo 1,019,602 nigba ti Nasir Gawuna ti APC ni iye ibo 890,705.

Ohun to wa maa n wu awọn eniyan lati gbọ nipa oṣelu Kano ni awọn alagbara baba isalẹ to yan aayo oludije ti wn n lulu ko wọle fun eyi to tumọ si wipe ẹni kọọkan wọn lee wọ̀ ibo to pọ daadaa.

Ẹni to jẹ baba isalẹ fun Kabir to jawe olubori ni gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ to si tun jẹ oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP, Rabiu Kwankwaso to jẹ pe to ba rọ sibi bayii, ọgọọrọ ero ni yoo wọ tẹle e lẹyin, o ni wọn pupọ lagbo ẹsin ati ti oṣelu bakan naa ti ẹgbẹ awọn alatilẹyin rẹ yii si ti ni orukọ fun ara wọn, “Kwankwasiya”.

Ni apa keji ẹwẹ, oludije ti APC, Gawuna ni gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ to si tun jẹ alagbara lẹgbẹ APC, Abdullahi Ganduje ẹni ti saa keji rẹ ọlọdun mẹjọ yoo pari ni ọjọ kọkandinlọgbọ́n oṣu kaarun.

Bawo ni wọn ṣe n lo agbara wọn latẹyinwa?

Fun ọpọlọpọ ọdun, Ganduje ati Kwankwaso ti jingiri ninu titako ara wọn lori “emi ni mo lagbara ju” lati dari ilu ti o pọ julọ ni gbogbo orilẹede Naijiria to si tun jẹ wipe awọn lo maa n ni iye oludibo to pọ ju ni Naijiria.

Lasiko idibo aarẹ to waye lọjọ́ Karundinlọgbọ́n oṣu Keji, ijọba ibilẹ mejidinlogoji ni Kwankwaso gẹgẹ bii oludije ipo aarẹ ti bori ninu gbogbo mẹrinlelogoji to wa ni Kano pẹlu ibo 997,279 nigba ti Bola Tinubu ti APC bori ni ijọba ibilẹ mẹfa to ku pẹlu ibo 517,341 amọ Kwankwaso ọhun lo gba ipo keji nigba ti gbogbo esi ibo aarẹ jade.

Ohun to tun wa fa oju ẹni mọra ni pe, Ganduje to jẹ gomina to n kogba wọle lo jẹ igbakeji fun Kwankwaso nigba to fi jẹ gomina tẹlẹri laarin ọdun 2011 si ọdun 2015 ko to di pe wn pinya lẹyin idibo ọdun 2015 eyi ti Ganduje ti jawe olubori gẹgẹ bii gomina titi di asiko yii.

Ṣaaju eyi Kwankwanso tun ti gomina Kano laarin ọdun 1999 si ọdun 2003.

Idi gaan niyi to ṣe jẹ pe awọn alagbara meji yii di opo idari gbogbo Kano mu gidi gan.

Ẹwẹ, latari gbogbo rogbodiyan to waye ni ibudo ti wọn ti kede esi idibo, ijọba ipinlẹ Kano ti kede ofin ma rin loju popo lati aarọ di alẹ ko ma baa si ipenija pe ẹnikẹni n ru ofin lẹyin ti idibo gomina ati ti ile aṣofin pari.

Ta ni yoo maa dari iye ibo ti yoo tu jade fun awọn oludije lọ́jọ́ waju bayii?

Amọ ibeere to n jẹ jade latẹnu ọpọ ọmọ Naijiria ni pe ki ni jijawe olubori ijọba tuntun yii tumọ si fun awọn ara Kano tori pẹlu ọgọọrọ iye ara ilu Kano, ibẹ ni awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP maa n foju si lara ju lati ko ibo to pọ ju.

Amọ o ṣeesee ko jẹ wipe ilu ti yi orin ti yipada bayii pẹlu ijọba tuntun to si le ṣeeṣe ko tun ni ṣe pẹlu ẹni ti yoo ma wa ni isakoso kiko ibo to pọ julọ lawọn eto idibo ti yoo waye lọjọ́ waju.

Boya ẹgbẹ Oṣelu NNPP toun ti gomina tuntun bi wọ́n ba ti bura wọle fun un yoo mọ le gbogbo ohun to ti wa nilẹ tẹlẹ ni abi yoo fẹ wa ajọ́ṣepọ pẹlu ẹgbẹ to wa lori oye aarẹ loke lọhun ko baa le jẹ anfani mundunmundun awan ipo nlanla ti yoo maa bu jade, ko sẹni to lee sọ.