Ohun tí mo soͅ fún àwoͅn ará Oyo sͅáájú ìdìbò ààreͅ nìyí – Seyi Makinde

Tinubu ati Makinde

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinleͅ Oyo, Seyi Makinde ti so bi o se jiroro peͅlu awoͅn ara ipinleͅ Oyo saaju idibo sipo aareͅ lorileͅede Naijiria.

Seyi Makinde ni o gbegba oroke ninu idibo sipo gomina to waye nipinleͅ Oyo la eͅgbeͅ oselu PDP, amoͅ oludije labeͅ eͅgbeͅ oselu PDP, Atiku Abubakar fidireͅmi ninu idibo sipo aareͅ, Bola Tinubu ti eͅgbeͅ oselu APC si gbegba oroke.

Ohun ti o ya awoͅn eniyan leͅnu nipe awoͅn gomina marun un leͅgbeͅ oselu PDP ni woͅn sͅatileͅyin fun eͅgbeͅ oselu APC lasiko idibo aareͅ naa, ti woͅn si tako oludije sipo aareͅ ti eͅgbeͅ oselu APC.

Ninu ifoͅroͅweroͅ peͅlu Channels TV , Seyi Makinde salaye pe kii se pe boya oun poͅn dandan fun awoͅn eniyan lati dibo yan Bola Tinubu amoͅ awoͅn eniyan onimoͅ ni awoͅn ara ipinleͅ Oyo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

‘’Awoͅn eniyan yan fun ara woͅn kii se wi pe a kan an nipa fun woͅn lati dibo yan eͅni kan tabi omiran.’’

‘’Agbara ati yan eͅni ti woͅn feͅ wa loͅwoͅ awoͅn araalu. Ni tootoͅ ohun ti mo soͅ fun awoͅn eniyan mi ni pe ki woͅn dibo fun iloͅsiwaju orileͅede Naijiria.

‘’Orileͅede Naijiria ti yoo ni iloͅsiwaju ko gboͅdoͅ fari apa kan da ikan si.’’

‘’Awoͅn ara ipinleͅ Oyo kii si sͅe oͅdeͅ ti eniyan le ti yipo-yipo lai weͅyin, awoͅn oͅloͅgboͅn eniyan lo wa nipinleͅ Oͅyoͅ.’’

‘’A dupeͅ pe aareͅ ti woͅn dibo yan ti wa, eͅ jeͅ ki a fi oͅwoͅ sowoͅpoͅ ki a joͅ sͅisͅeͅ, ki idagbasoke le ba orileͅede Najiria.’’

‘’Awa gomina labeͅ G5 ko fi isͅeͅ wa sere rara, ohun ti a bere fun ni ohun ti ofin soͅ paapaa ofin eͅgbeͅ oselu PDP.

‘’Ofin eͅgbeͅ fi aye gba ki ipo maa yi lati eͅkun kan de o miran, amoͅ woͅn koͅ lo mu wa ja fun ohun ti o toͅ’’

Seyi lẹ́ẹ̀kànsi! Makinde la Folarin mọ́lẹ̀, wọle ìbò gómìnà Oyo fún sáà kejì

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Gomina Seyi Makinde ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo jawe olubori ninu idibo gomina ipinlẹ Oyo to waye lọjọ Satide.

Ajọ eleto idibo, INEC lo kede Makinde gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo gomina ipinlẹ Oyo ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta.

Gẹgẹ bi esi ti INEC kede, Makinde ni ibo 563,756, nigba ti Folarin ẹgbẹ APC sẹ ipo keji pẹlu ibo 256,685.

Adebayo Adelabu ẹgbẹ Accord lo ṣe ipo kẹta pẹlu 38,357, nigba ti Akinwale Tayo LP to ṣe ipo kẹrin ni ibo 1500.

Bayo Adelabu ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Bayo Adelabu ko jawe olubori ninu ijọba ibilẹ kankan

Gomina Makinde to ti ṣe saa kan tẹlẹ bori ni ijọba ibilẹ mọkanlelọgbọn ninu ijọba mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Oyo.

Folarin to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu ijọba ibilẹ meji, Orelope ati Irepodun.

Bakan naa, oludije ẹgbẹ osẹlu Accord, Adelabu ko jawe olubori ninu ijọba ibilẹ kankan.

Oludije ẹgbẹ LP, Tayo naa ko jawe olubori ninu ijọba ibilẹ kankan.

PDP: 13139

APC: 9,445

PDP: 28,920

PDP: 18389

APC: 7,377

PDP: 30,444

IBADAN NORTH

APC: 5,678

PDP: 10,845

IBADAN NORTH EAST

PDP: 29396

IBADAN NORTH WEST

PDP: 19007

IBADAN SOUTH EAST

PDP: 23585

IBADAN SOUTH WEST

PDP: 31273

IBARAPA CENTRAL

APC: 6,287

PDP: 10,491

IBADAN EAST

PDP: 11125

IBARAPA NORTH

APC: 11,883

PDP: 39,658

APC: 7,865

PDP: 19,284

PDP: 15554

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí