NÍ YÀJÓYÀJÓ Ohun táa mọ̀ nípa èsì ìbò Adamawa àti Aisha Binani tí ayé ń pariwo rẹ̀ lórí ayélujára

Copyright: Others

Láti ọjọ́ Àìkú, ọjọ́
Kọkàndínlógún oṣù kéjì tó jẹ́ ọjọ́ kejì tí ètò ìdìbò gómìnà wáyé káàkiri àwọn
ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni àwọn èsì ìdìbò ti ń jáde.

Àjọ tó ń mójútó
ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ti kéde èsì ìbò ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi mẹ́wàá tó fi mọ́
Eko, Ogun, Kwara, Oyo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní báyìí, àkójọpọ̀
àwọn èsì ìbò ṣì ń tẹ̀síwájú ní àwọn ìpínlẹ̀ kan bíi Kano, Enugu, Rivers àti
Adamawa.

Ṣaájú ni àwọn
ènìyàn ti ń gbé ìròyìn lórí ayélujára pé olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives
Congress, Aisha Binani ti gbégbá orókè èsì ìbò ní ìpínlẹ̀ náà tí àwọn ènìyàn sì
ti ń kii kú oríire lórí ayélujára.

View more on twitter
View more on twitter

Ẹ̀wẹ̀, INEC ṣì ń ṣe àkójọ èsì ìbò ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́, tí wọ́n sì ti kéde èsì ìbò ní ìjọba ìbílẹ̀ ogún nínú ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún ló wà ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Nínú èsì ìbò tí INEC ti kéde báyìí, gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ahmadu Fintiri tó ń wá sáà kejì lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ló ń léwájú pẹ̀lú ìbò 401,115.

TÍ Aisha Binani tẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC sì ń tẹ̀le pẹ̀lú ìbò 365,508 èyí tó mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn jẹ́ 35,607.

Ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlá ni gómìnà Fintiri ti mókè tí Aisha Binani sì mókè ní ìjọba ìbílẹ̀ méje.

Ìjọba ìbílẹ̀ kan tó kù kí wọ́n kà ni Fufore, níbi tí wọ́n ti ṣaájú kà àmọ́ tí wọ́n dá aṣojú INEC tó ka èsì ìbò náà padà nítorí kùdìẹ̀kudiẹ tó wà nínú èsì ìbò tó kà.

Èyí ló mú kí INEC sún kíkéde èsì ìbò Fufore sí aago méjìlá ọjọ́ Ajé àti kíkéde ẹni tó bá gbégbá orókè.

Àwọn jàǹdùkú yabo ibùdó tí ìbò kíkà ti ń wáyé

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ di bó ò lọ o yà fún mi nígbà tí àwọn jàǹdùkú kan yabo ibùdó tí INEC ti ń ṣe àkójọ èsì ìbò ní ìlú Yola nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ INEC fẹ́ lọ fún ìsinmi ní aago méjì òru.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló ṣe akitiyan láti lé àwọn ènìyàn náà lọ kí àwọn kan tó le kúrò ní ibùdó náà.