Ta ni Maryam Shetty tí Ààrẹ Tinubu yọ orúkọ rẹ nínú àwọn tó fẹ yan sípò Mínísítà?

Aworan Matyam Shetty

Oríṣun àwòrán, Facebook/Maryam Shetty

Aarẹ Bola Tinubu ti yọ orukọ arabinrin Maryam Shetty kuro ninu awọn to forukọ wọn ṣọwọ fún ayẹwo sipo Minisita.

O fí ẹlòmíràn paarọ rẹ tó sì tún kede orukọ èèyàn kan sí lara awọn to fi ṣọwọ sipo niwaju ile.

Senetọ Godswill Akpabio to jẹ aarẹ ile aṣofin agba lo kede ọrọ yi bo ṣe wà nínú iwe ti Ààrẹ Tinubu fi ṣọwọ si ile lọjọ Ẹti.

Orúkọ awọn meji ti ààrẹ fi ṣọwọ ni Dr Maria Mairiga ati Festus Keyamo.

Mairiga ni wọn fi paarọ Maryam Shetty.

Aarẹ Ile ko salaye idi ti ààrẹ fi yọ orukọ Shetty kuro to sì fi ẹlòmíràn paarọ rẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ,lowurọ ọjọ Ẹti yi lawọn eeyan kan lati ipinlẹ Kano ko ara wọn jọ niwaju ile aṣofin ti wọn si fẹhonu han lori fifi orukọ Shetty sinu awọn ti aarẹ fẹ yan sipo Minisita.

Lọjọru aarẹ Tinubu fi orukọ abala keji awọn to fẹ yan sipo ranṣẹ sile ki wọn baa le ṣayẹwo wọn fun iyansipo Minisita.

Ninu orukọ abala keeji yi la ti ri awọn Gomina tẹlẹ ri, awọn ọmọ ile aṣfin ati awọn ọdọ.

Ninu gbogbo awọn to wa ninu abala keji yi orukọ ti Maryam Shetty lati ipinlẹ Kano ni ẹnu ko sin lara rẹ.

Ki wa lo de ti ọrọ fi ri bẹẹ ati pe tani arabinrin Maryam Shetty yi gaan?

Aworan Maryam Shetty

Oríṣun àwòrán, facebook/Maryam Shetty

Ọmọ bibi ilu Kano ni Maryam Shetty.

Wọn bi lọdun 1979 to si kawe gboye ni fasiti Bayero ni Kano lẹka ilera.

Bẹẹ lo tẹsiwaju lọ gboye giga ni fasiti Stratford ni ilẹ Gẹẹsi nibi to lọ kọ nipa imọ itọju eegun fawọn elere idaraya.

O wa lara awọn dokita to ba ikọ elere idaraya Naijiria lọ si idije agbaye World Athletics Championships ni London lọdun 2012.

Bakna naa ni Maryam ti ṣe orisi eto idanilẹkọ lagbaye to fi mọ lorileede Amẹrika.

Bo ti lẹ jẹ wi pe ko dije dupo kankan ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo jẹ.

Koda o wa lara awọn to jijọ polongo idibo faarẹ Bola Tinubu nigba naa gẹgẹ bi ọmọ igbimọ ipolongo.

Gbajumọ ti ọpọ eeyan mọ lori ayelujara lo si tun jẹ.

Ki lawọn eeyan n sọ lati igba ti ikede yi ti jade?

Loju opo Twitter, niṣe lawọn eeyan n gba ọrọ Maryam Shetty bi ẹni gba igba ọti lati igba ti ile aṣofin ti kede pe aarẹ loun fẹ ki wọn paarọ orukọ rẹ pẹlu ti ẹlomiran.

Ohun ti ọrọ tawọn eeyan n sọ lori Twitter si da lori pe ṣe o yẹ tabi ko yẹ ki wọn yọ orukọ rẹ.

Die ree ninu nkan tawọn eeyan n sọ

Mo dupẹ lọwọ aarẹ pe o yọ orukọ mi

Ninu esi rẹ si iṣẹlẹ yi Maryma Shetty loun dupẹ lọwọ aarẹ lori eyikeyi igbesẹ to ba gbe lori yiyọ orukọ rẹ to si fi ti Dr Mairiga paarọ.

O fi ọrọ yi sita loju opo rẹ ni Twitter.

O ni ”mo ba Dr Mairiga yọ bẹẹ si ni mo dupẹ lọwọ awọn aṣsaju ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Kano ni paapa Abdullahi Ganduje to jẹ olori ẹgbẹ wa ni Kano”