Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò

Awon Ololufe to n fẹnu kora

Oríṣun àwòrán, Tim Macpherson

Iwadii fihan pe ti eniyan ba fi ẹnu ko ara fun iṣẹju aaya mẹwa, o kere tan ọgọrin miliọnu kokoro ni awọn mejeeji yoo ti pin fun ara wọn.

Ọna kan gboogi ti awọn eniyan fi n fi ifẹ han si ara wọn ni ifẹnukonu, amọ ki lo n ṣẹlẹ laarin awọn ololufẹ lasiko ti wọn ba n fi ẹnu kora yii?

O dara ki awọn ololufẹ fẹran lati maa fi ẹnu kora, amọ ọpọlọpọ kokoro aifojuri ni wọn ma n fun ara wọn lasiko yii.

Bi o tilẹ ṣe pe kii ṣe ifẹ inu wọn ni lati fun ẹnikeji wọn ni kokoro, amọ orisiri kokoro to le ni ẹẹdẹgbẹrin ni wọn lee fun ara wọn lasiko yii.

Ohun kan pato to mu ki o ṣeeṣe fun kokoro lati tan ka ni bi ẹnu eniyan ṣe ri, eleyii to fi aye gba ki kokoro gbinlẹ si tabi tan kaakiri ẹnu.

Iru awọn kokoro aifojuri wo lo lee wọ ẹnu rẹ lasiko ifẹnukoẹnu?

Nitori ẹnu ati ahọn eniyan kun fun orisirisi kokoro, ti o ba fi ẹnu ko ẹlomiran, kokoro ẹnu enikan le bọ si ti ẹlomiran, ti yoo si maa dagba si ninu ara.

Iwadii tun fihan pe lasiko ti eniyan ba fi ẹnu ko ara fun iṣẹju aaya mẹwa, o kere tan ọgọrin miliọnu kokoro ni awọn mejeeji yoo ti pin fun ara wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkan lara awọn kokoro aifojuri ti o wa ni ẹnu eniyan lati igba ti wọn ti bii ni ‘microbiota’, eleyii ti o ma n yipada bi eniyan ba ṣe n dagba si.

Iru igb eaye ti eniyan n gbe bii siga mimu, iru oogun ti eniyan n lo ati iru ounjẹ ti eniyan n jẹ lee mu ki kokoro ẹnu yii gberu sii tabi ki o dinku.

Ọjọ ori ati ẹjẹ pẹlu iran naa ma n ṣakoba fun awọn kokoro ẹnu ti eniyan ni.

Anfaani wo lo wa ninu kokoro aifojuri to wa ni ẹnu eniyan?

Bi o ti wu ki awọn kokoro aifojuri yii pọ to wọn ni awọn anfaani ti wọn n ṣe fun ara ni igba miran.

Awọn kokoro aifojuri ma n jẹ ki eroja ‘immune’ ara ji pepe.

Wọn ma n ran ẹda ounjẹ ninu lọwọ lati tete jẹ ki ounjẹ da ninu.

Bakan naa ni wọn n ṣeranwọ lati ṣe adinku fun aisan ẹjẹ riru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo ma n ṣẹlẹ lasiko ifẹnukonu laarin ololufẹ meji?

Ni ọpọ igba, bi awọn ololufẹ meji ṣe sunmọra to lasiko ifẹnukonu ma n pẹlu ohun to n jẹ ki kokoro aifojuri yii kuro ni ara enikan si omiran.

To si ṣeeṣe ki a bori awọn arun yii ti a ba kiyesi ara, eleyii to niiṣe pẹlu bi ara ba ṣe gba kokoro aifojuri si.

Lasiko ifẹnukonu, oye kokoro aifojuri to ba ti wole si ara eniyan ma n lọ si ọna ọfun taarata ni, nigba ti awọn miran ma n duro si ẹnu.

Ohun ti eleyii tun mọ si ni pe lọpọ igba, o ṣoro fun awọn kokoro yii lati duro si ẹnu eniyan lasiko ifẹnukonu, amọ eniyan ni lati ṣọra nitori awọn miran ma n sa pamọ si kọrọ ẹnu.

Kini awọn ijamba to rọ mọ kokoro aifojuri yii?

‘Biofilm’ ni wọn n pe kokoro ‘bacteria’ ma n fa si ẹyin lasiko ifẹnukonu, eleyii ti o ma n ṣoro lati tete bojuto.

Suga ninu ounjẹ ati awọn nkan miran ni kokoro yii ma n lo lati fi ṣe ara rindin, amọ o le fa ki ẹyin bajẹ abi ko jẹra.

Nitori naa jijẹ suga ma n fa aisan ẹyin, eleyii to le mu ki ẹyin eniyan jẹra tabi ki o bajẹ.

Bakan naa ni aisan miran ti ifẹnukonu ati kokoro aifojuri ma n fa ninu ara ni ‘Streptococcus mutans’.

Njẹ ọna abayọ wa lati bori awọn arun wọn yii?

Ti erigi to wu abi ẹyin to ti bajẹ ko ba tete ri iwosan gba, abi ki wọn yọ ọ kuro, o le jẹ aisan ti yoo mu ki gbogbo ẹnu wu, eleyii ti wọn n pe ni ‘periodontitis.’

Bakan naa ni ifẹnukonu le fa ‘bacteria’ to n mu ki ẹnu run, amọ ti eniyan ba n ṣe imọtoto ẹyin ati ahọn , to si n fọ ẹnu ni orekoore, o ṣeeṣe ki ara rẹ pada bọ si ipo.

Nitori naa o pọn dandan ki a fọ ẹyin wa ni wẹrẹ ti a ba ti jẹun tan, ki arun le dinku ni ara.

Bakan naa ni ifẹnukora le mu ki ololufẹ meji ma a jọ ara wọn nitori wọn ti jọ pin kokoro aifojuri kan naa ninu ara wọn.

Bi o tilẹ jẹpe, ifẹnukonu ma n mu ki ifẹ gbooro laarin ololufẹ meji, eniyan gbọdọ mọ iru ẹni ti oun fi ẹnu ko lẹnu nitori wọn le e pin aisan naa fun ara wọn, nitori naa ni ki awọn ololufẹ ma a ṣọra ṣe.