Fídíò, Àṣírí ìdí tí Ọba Ogboni kò fi lè dé adé lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Yorùbá tún nìyí – Oba Adeyinka Arifanlajogun, Duration 5,54

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ọ̀wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Olódùmarè ni Ogboni máa wà bí ó bá re ibi àgbà ń rè – Oba Ogboni

BBC Yoruba rinrinajo de aafin Ọba Ogboni Igba Iwasẹ, ọpọ itan ti awọn eeyan ko mọ ni pa ẹgbẹ Ogboni lo jade.

Adeyinka Arifanlajogun to jẹ Ọba Ogboni bu ẹnu atẹ lu ọpọlọpọ ohun tawọn eeyan maa n sọ nipa ẹgbẹ naa jakejado agbaye.

Bi Ogboni igba akọkọ ṣe bẹrẹ ati bi aweọn baba nla baba wọn ṣe bẹrẹ ẹgbẹ naa to fi di pe o n gberu sii titi to fi di eyi to n ni ẹka gẹgẹ bii ijọ awọn ẹlẹsin Kristẹni ṣe tan kaakiri lode oni.

“Ogboni pọ, ṣugbọn Ogboni igba iwasẹ lo bi awọn to wa kaakiri lode oni.

Gẹgẹ bi ṣọ́ọ̀ṣì ṣe wa kaakiri kaakiri naa ni awa naa ni ẹka”.

Ọba Adeyinka ni Ọlọrun kan naa ni awọn Kristẹni, Muslumi ati Ologboni n sin, ọna ti wọn n gba ke pee lo yatọ.

Bakan naa o ni ko si Ologboni to maa n ku ni kekere ayafi ti ko ba ṣee tọkan tọkan.

Adeyinka ni ni Ọba Ogboni lo maa n fi gbogbo Ọba jẹ nilẹ Yoruba awọn ko si ki n yọ nkankan lara ẹnikẹni gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n sọ pe bi ọkan lara wọn ba ku, o ni nkan ti wọn maa n lọ yọ lara rẹ.

“Irọ patapata ni, ko si nkan to jọọ, awọn to ba n sọọ nita pe Ogboni maa n yọ nkan lara eeyan o mọ nkan ti wọn n sọ”.

“Ọba Ogboni ko ni ẹtọ lati de ade rẹ lọ siwaju Ọba Yoruba toripe afọbajẹ lawa Ogboni”.

Bakan naa, Adeyinka ni pẹlu iwadii jinjin ti awọn maa n ṣe fun oṣu mẹfa ki ẹnikẹni to lee darapọ mọ awọn, ko lee si ẹlẹgbẹ okunkun lara awọn.

O ni ọpọ Kristẹni ati Musulumi lo maa n wa darapọ mọ awọn.