Ìbẹ̀rùbojo wọ ìlú méjì ní ìhà Àrìwá Naijiria, Boko Haram tún ti gbàjọba níbẹ̀!

Yan bindiga

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn ara ilu Sabon Birni ni ipinlẹ Sokoto ti ke gbajare sita pe awọn agbebọn ti gbakoso ilu wọn eleyii to mu ki ọpọlọpọ eniyan sa kuro lọ si Niger.

Awọn aṣofin mejeeji to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Sabon Birni sọ pe ijọba ibilẹ ọhun ti wa ni abẹ iṣakoso ikọ Boko Haram bayii nitori wọn ti ba gbogbo ojuko ibugbe awọn ologun jẹ nibẹ.

Eyi ko ṣẹyin iroyin pe awọn agbebọn ti pa awọn ọmọ ogun mẹtadinlogun ati araalu meji ni opin ọsẹ.

“Lọwọlọwọ, a wa loju ibọn awọn agbebọn ni Sabon Birni”. Eyi ni iroyin ti BBC gbọ lẹnu eeyan ọkan lara awọn ti awọn agbebọn ko ni papa mọra ti wọn kan si.

Kọmiṣọna fun eto aabo nipinlẹ Sokoto tẹlẹri, Garba Moyi ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, amọ wọn n duro de ikọ ologun lati fi iroyin naa lede.

”Lootọ ni a ti gbọ iroyin nipa ikọlu si ipinlẹ Sokoto ati awọn agbegbe ti awọn agbebọn ti ba awọn ẹrọ ayelujara jẹ nibẹ, ti ko si si bi awọn eniyan ṣe le ba ara wọn sọrọ”.

”Ilu marun un ti Kangara ati Katsira wa lara wọn ni wọn ṣekọlu si, ti wọn si pa eniyan mẹrin, ti awọn mẹfa si n gba itọju lọwọ ni ileewosan.

Bakan naa ni wọn ni awọn agbebọn naa dana sun awọn meji to farapamọ si ile ounjẹ lasiko ikọlu ọhun, ti wọn si jade laye.

Nibayii ko si eto aabo kankan mọ ni awọn agbegbe ti wọn ṣekọlu si yii nitori wọn ti pa awọn ẹṣọ alaabo to wa nibẹ, ti awọn araalu naa si ti fi ẹsẹ fẹ lọ si ẹyin odi lorilẹede Niger.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn araalu sakuro ni Yobe lẹyin ikọlu Boko Haram

Ko tan si ipinlẹ Sokoto nikan, awọn agbebọn yii tun ṣekọlu si agbegbe Babangida ni ipinlẹ Yobe.

Iṣẹlẹ yii ti mu ki ọpọlọpọ awọn araalu sa asala fun ẹmi wọn kuro nibe lai ti pe oṣu kan ṣẹyin ti awọn agbebọn yii ṣekọlu si ibẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn agbebọn yii ma n wa ni ọgọọrọ lati wa ṣekọlu si agbegbe naa, eleyii to fi mọ ilu Ọga Agba ọlọpaa, Usman Baba Alkali, ti awọn agbebọn naa si gbe asia wọn sibẹ.

Bakan naa ni awọn agbebọn ti ba awọn ẹrọ ayelujara jẹ nibẹ, ti ko si si bi awọn eniyan ṣe le ba ara wọn sọrọ lori ẹrọ ilewọ tabi ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ