Bàbá, ọmọ àti aládùúgbò kú sí ṣálángá ni Kano

Aworan oṣiṣẹ kan ninu iho

Oríṣun àwòrán, Getty

Baba ẹni ọgọta ọdun kan ti orukọ rẹ n jẹ Danjuma Bilack, ọmọ rẹ, Ibrahim ati aladuugbo wọn kan ni wọn pade iku ojiji lọjọ Aiku nigba ti wọn ja si ṣalanga.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii niṣẹlẹ aburu naa waye.

Ẹrọ ibanisọrọ Mallam Danjuma lo ṣeṣi ja si ṣalanga oniho naa nigba ti baba yii wa ninu ile igbọnsẹ ọhun, o si gbiyanju lati wọnu rẹ lọọ mu un.

Nigba ti baba denu iho, ko le jade mọ.

Ọmọ rẹ, Ibrahim, ẹni ọdun marundinlogoji (35) gburoo baba rẹ lati ile igbọnsẹ, o si gbiyanju lati fa a yọ.

Nibi igbiyanju naa ni Ibrahim paapaa ti ṣubu si ṣalanga, toun naa ko le jade mọ.

Aládùúgbò wọn tó fẹ́ẹ́ yọ wọ́n náà lọ sí i

Ṣalanga oniho

Oríṣun àwòrán, Getty

Agbẹnusọ ajọ panapana ni Kano, Saminu Yusuf to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, sọ pe ọkunrin kan, Aminu T Gaye toun gbe lagbegbe naa ba iṣẹlẹ yii lọ pẹlu.

Saminu ṣalaye pe Ọgbẹni Gaye wa lati yọ baba atọmọ naa ni, ṣugbọn niṣe loun paapaa ha sinu iho ṣalanga naa.

‘’Nigba ti awọn oṣiṣẹ panapana yoo fi gba ipe pajawiri lori iṣẹlẹ naa, awọn mẹtẹẹta ti ku.

’”Wọn o mọ nnkan kan mọ nigba ti wọn yoo fi gbe wọn jade.

’”Awọn dokita si fidi ẹ mulẹ pe wọn ti ku’’

Bẹẹ ni Agbẹnusọ ajọ panapana ni Kano naa ṣalaye.

Nilẹ Adulawọ, awọn eeyan ṣi n lo ṣalanga oniho lati fi ṣegbọnsẹ.

Bakan naa lawọn mi-in ṣi n ṣe tiwọn sinu igbo, inu odo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni 2018, ọmọde mẹfa ni wọn ko jade ni ṣalanga nileewe Kisulisuli, lorilẹ-ede Kenya, nigba ti iho naa gbe wọn mi.