EFCC nawọ́ gán Hadi Sirika, alákòóso ètò ìrìnàjò òfúrufú tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn lílu ₦7b ní pónpó

Hadi Sirika

Alakooso fun eto irinajo ofurufu ni Naijiria tẹlẹ, Hadi Sirika, ni ajọ EFCC ti nawọ gan bayii.

Nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin , ọdun 2024 ni Sirika gunlẹ si ọfiisi EFCC lori ẹsun ṣiṣẹ owo to le ni biliọnu mẹjọ naira mọkumọku.

Ajọ naa sọ pe Hadi Sirika wa lahamọ awọn bayii to n tan imọlẹ si ẹsun owo to to N8,069,176,864.00, ti wọn fi kan an pe o ṣe mọkumọku nigba to n ṣakoso ọọfisi naa.

Gẹgẹ bi EFCC ṣe wi, aburo Hadi Sirika, Abubakar Sirika, ni minisita tẹlẹ naa ko apa kan owo yii fun lori agbaṣe iṣẹ.

Ṣugbọn Abubakar ko ṣiṣẹ kankan.

Oṣiṣẹ ijọba ni aburo rẹ yii, ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Engirios Nigeria Ltd lo tun da silẹ funra rẹ.

Awọn ẹsun bii igbimọpọ, aṣilo ipo, kiko owo ilu gba ibo mi-in, fifi owo le iye to yẹ ko pari iṣẹ, yiyi adehun pada ni wọn ka si alakooso tẹlẹ naa lẹsẹ.

A ti mú Abubakar Sirika náà sátìmọ́lé – EFCC

Agbaṣe iṣẹ mẹrin lo yẹ kowo ọhun wa fun gẹgẹ bii alaye EFCC.

Nigba ti Abubakar ti wọn gbe e fun ko si ṣe e, wọn lawọn ti mu oun naa sọdọ bayii lati wa sọ tẹnu rẹ.

“Hadi gbé àgbàṣe iṣẹ́ fún àbúrò rẹ̀, Abubakar, ó sì mọ̀ p;é òṣìṣẹ́ ìjọba ni”

Oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele kẹrindinlogun ni Abubakar Sirika nileeṣẹ to n ri si ipese omi.

Ileeṣẹ naa lo wa lati ọdun 2000, ṣugbọn o tun da ileeṣẹ kan silẹ to pe ni Enigirios Nigeria Ltd.

Awọn apo ikowosi meji, Zenith ati Union bank ni wọn ni Abubakar n kowo si fun ileeṣẹ Enigirios rẹ, oun si ni alakooso awọn akanti naa.

Gbogbo eyi ni ẹgbọn rẹ, Hadi Sirika mọ, ṣugbọn o tun n kowo ijọba apapọ fun un.

Àlàyé EFCC nípa owó náà

‘’Ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni Hadi Sirika gbeṣẹ akọkọ faburo rẹ lati fi kọ ibi tawọn ero yoo maa jokoo si ni papakọ ofurufu Katsina.

1, 345, 586, 500.00 lowo naa.

‘’Lọjọ kẹta ọsu kọkanla 2022, N3,212, 258, 930.00 ni Hadi Sirika tun san sapo ileeṣẹ aburo rẹ lati fira irinṣẹ fun ileewe ẹkọ irinajo ofurufu ni Zaria.

‘’Iṣẹ kẹta lo gba lọjọ kẹta, oṣu keji ọdun 2023.

Abubakar loun fẹẹ fowo naa ra ẹrọ agbenigunke (lift), amuletutu (AC) ati ile to loun yoo kọ fun ẹrọ amunawa.

Bẹẹ naa lo gba ẹlẹẹkẹrin lai ṣe ohunkohun titi dasiko yii’’

Biliọnu mẹta naira (3bn)ni apapọ owo ti Abubakar Sirika gba bi EFCC ṣe ṣalaye.

Ẹgbọn rẹ, Hadi Sirika lo si san an si akanti rẹ .

Yahaya Bello mú $720,000 lápò ìjọba láti sanwó fásitì ọmọ rẹ̀ nílẹ̀ òkèèrè bó ṣe ku ọjọ́ díẹ̀ kó kúrò lórí àléefà – EFCC.

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Alhaji Yahaya Bello

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, ti sọ pe gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello gba owo ti iye rẹ to $720,000 lati fi san owo ile ẹkọ ọmọ rẹ lasiko to ku iwọnba ọjọ perete ko fi ipo gomina silẹ.

Ọga agba EFCC, Ola Olukoyede lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin ni olu ọọfisi ajọ naa to wa niluu Abuja.

Olukoyede sọ pe Bello gba owo naa lapo ijọba, o si gbe lọ si apo awọn to n paarọ owo ‘Bureau de Change’ gẹgẹ bii asansilẹ owo ile ẹkọ ọmọ rẹ.

“Ṣe o yẹ ki irufẹ ajẹbanu bẹẹ maa ṣẹlẹ ni ipinlẹ to toṣi bii Kogi, Ẹ si ro pe mo maa dakẹ?”

O ni “Gẹgẹ bii gomina, o mọ pe oun ti fẹ fi ipo silẹ, o gbe owo lati inu apo ijọba si apo awọn Bureau de Change lati fi san owo ile ẹkọ ọmọ rẹ ti ko tii bẹrẹ.

“Owo naa jẹ nnkan bii $720,000 tabi ju bẹẹ lọ pẹlu imọtẹlẹ pe oun yoo fi ipo gomina silẹ laipẹ.

“Ṣe o yẹ ki irufẹ nnkan bẹẹ maa ṣẹlẹ ni ipinlẹ to toṣi bii Kogi? Ẹ si ro pe mo maa dakẹ?

“Awọn kan sọ pe awọn kan lo n lo mi lati gbogun tii, ṣe lọjọ ori mi yii ni ẹnikan yoo maa lo iru mi?

“Emi kọ ni mọ bẹrẹ ẹjọ rẹ, mo jogun ẹjọ naa ni, mo si bere fun faili rẹ lati tẹsiwaju ẹjọ naa latari awọn nnkan ti mo ri nibẹ.

“Mo maa ri daju pe Bello foju bale ẹjọ”

Alaga ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu naa sọ siwaju si pe oun yoo ri daju pe oun ṣe ẹjọ gomina ana ọhun, ati pe oun yoo kọwe fi ipo alaga EFCC silẹ ti ko ba foju bale ẹjọ.

O fi kun pe gbogbo awọn to dena EFCC lati mu Yahaya Bello naa yoo foju wina ofin.

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ki ni yahaya Bello ṣe?

Ẹsun mọkandinlogun ọtọtọ ni EFCC fi kan Bello, eyii to da lori kiko owo ijọba lọna aitọ ati lilu owo ilu ni ponpo, ti iye owo naa si le ni ọgọrin biliọnu naira.

Olukoyede ni oun atawọn oṣiṣẹ oun ti ṣetan lati fọ naijiria mọ lọwọ iwa ajẹbanu lai ro ti awọn alatako ati ajẹnilẹsẹ to n gbogun ti EFCC.

Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lati oṣu Kinni, ọdun 2016 si oṣu Kinni, ọdun 2024 yii ko to gbe ijọba kalẹ fun Usman Ododo lati inu ẹgbẹ rẹ, APC.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni EFCC yabo ile gomina ana ọhun niluu Abuja lati fi panpẹ ofin mu amọ o ti na papa bora.

Lẹyin naa ni wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa lẹyin to sa fun ofin.