Bí ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Baba Ijesha pè lórí ẹ̀wọ̀n tó ń ṣe, ṣe lọ rèé

Aworan Baba Ijesha

Gbajugbaja adẹrinpoṣonu onitiata, Olarenwaju James ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti rọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Eko wi pe ko yi idajọ ile ẹjọ giga eyi to ju u sẹwọn danu lori ẹsun ifipabọmọde lopọ.

Ni ọjọ kẹrinla oṣu Keje ọdun 2022 ni ile ẹjọ kan niluu Eko dajọ pe o jẹbi ẹsun ifipabanilopọ pẹlu ọmọdebinrin kan, ti ile ẹjọ naa si ran an lẹwọn ọdun marun.

Amọ, lẹyin naa ni Baba Ijesha morile ile ẹjọ kotẹmilọrun lati yi idajọ ile ẹjọ giga yii danu.

Amọ, lẹyin naa ni Baba Ijesha morile ile ẹjọ kotẹmilọrun lati yi idajọ ile ẹjọ giga yii danu.

”Princess lo ni ki Baba Ijesha wa ṣe ‘skit’ pẹlu rẹ nile”

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori ẹjọ kotẹmilọrun naa, Ọgbẹni Kayode Olabiran, to jẹ agbẹjọro Baba Ijesha sọ pe Damilola Adekoya tawọn eeyan mọ si Princess ”lo pe Baba Ijesha pe ko wa ṣere nile rẹ lori ifipabanilopọ, kii ṣe pe o fipa ba ọmọde lopọ.

Princess gan an kọ ọ sinu iwe to kọ ni agọ ọlọpaa pe oun loun pe Baba Ijesha wi pe ko wa bawọn ṣere itage nile oun.

Bakan naa, ninu ọrọ ti a bi ọmọ naa pe kilode ti ko fi sa jade nigba ti Baba Ijesha fẹ maa fọwọ kan an, o ni kamẹra ko ni le gbe oun ti oun ba le sun kuro nibi toun jokoo si.

Koda, fọnran ti o lu ori ayelujara pa nigba yẹn, ohun ti wọn ni ki Baba Ijesha ṣe lo ṣe ninu rẹ.”

Aworan Baba Ijesha

Idi ti Baba Ijesha fi pe ẹjọ kotẹmilọrun ree

Agbẹjọro Baba Ijesha ni ”awijare wa ni pe gbogbo nnkan ti adajọ sọ ni ile ẹjọ giga ko tẹ wa lọrun.

A o le faramọ tori a ri pe idajọ yẹn kudiẹ kaato, atotonu ijọba to jẹ olupẹjọ nikan ni adajọ fi ṣe idajọ rẹ.

Ile ẹjọ ko tiẹ ya si gbogbo nnkan ti awa sọ rara, bo tilẹ jẹ wi pe o yẹ ki ile ẹjọ ni arojinlẹ lori awọn nnkan ti a sọ ki wọn ṣi ṣe agbeyẹwo rẹ pẹlu.

Idi eyi gan an ni a fi pe ẹjọ kotẹmilọrun ti a pe yii.

Akọkọ, ninu iwe ti ọmọ yii kọ ni agọ ọlọpaa, o ṣo pe ọmọ ọdun mẹrinla loun, amọ, o sọ fun ile ẹjọ pe ẹni ọdun marundinlogun loun.

Amọ, ile ẹjọ sọ nigba naa pe, ki ba a jẹ ọmọ ọdun mẹrinla tabi mẹẹdogun, ọmọkekere si ni labẹ ofin.

Ṣugbọn, ohun ti awa n sọ ni pe aridaju gbọdọ wa ki ẹ to le sọ pe ọmọde ni ẹnikan.

O yẹ ki baba tabi mama ọmọ yẹn le sọ ọjọ ati ile iwosan ti wọn bi ọmọ yẹn si.

Ẹri keji ni pe o yẹ ki o ni iwe ẹri ọjọ ibi rẹ lọwọ, wọn kuna lati mu ẹri yii wa sile ẹjọ.

Nitori naa, ọmọ yii le ju ọmọ ọdun mẹrinla tabi mẹẹdogun ti ile ẹjọ sọ lọ.’’

Ẹwẹ, adari ẹka igbẹjọ nipinlẹ Eko, Ọmọwe Babajide Martins rọ ile ẹjọ lati yi awijare agbẹjọro Baba Ijesha danu tori ko lẹsẹ nlẹ.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo dajọ naa laipẹ.

Bi Baba Ijesha ṣe rí ẹ̀wọ̀n he lórí ẹ̀sún ìfipábá ọmọdé lọ̀pọ̀

Ile-ẹjọ pataki kan ti Ikeja niluu Eko dájọ́ pe gbajugbaja oṣere Olanrewaju James, ti a n pe ni Baba Ijesha jẹbí esun ifipa banilopo ọmọ ọdun merinla kan.

Adajo Oluwatoyin Taiwo, ninu idajo wakati meji lojo òní , da Baba Ijesha lebi fun iwa aisedede si omo kan, ilokulo ibalopo, ati igbidanwo ifipabanilopo ibalopo.

Adajo Taiwo ni awọn olupẹjọ fidi rẹ mulẹ pe lootọọ ni Baba Ijesha fi ipa ba ọmọdebinrin lopọ.

Odun 2021 ni igbẹjọ naa bẹrẹ lẹyin ti akẹgbẹ Baba ijesha, Princess wọ ọ lọ sile ẹjọ nitori pe ẹrọ ayaworan CCTV to wa ninu ile rẹ tu aṣiri bi Baba Ijesha ṣe n fi ọwọ riun ọmọdebinrin ti Princess jẹ alagbatọ fun lara ati ni kake gẹgẹ bi igbaradi lati baa ni ajọṣepọ.