Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta rí ẹ̀wọ̀n he ní Ilorin fẹ́sùn ìfipábánilòpọ̀

ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Others

Ilé ẹjọ́ gíga ìpńlẹ̀ Kwara tó fi ìlú Ilorin ṣe ibùjókòó ti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta kan lẹ́wọ̀n fẹ́sùn wí pé wọ́n fipá bá pá ìbátan ọ̀kan nínú wọn lòpọ̀.

Adájọ́ Adenike Akinpelu ní ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn náà jẹ̀bi ẹ̀sùn méjì tí wọ́n kà sí wọn lọ́rùn.

Ní agbègbè Adangba, ìjọba ìbílẹ̀ Ilorin East ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilòpọ̀ náà ti wáyé.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Omotosho Yahaya, Mustapha Ahmed àti Mustapha Ridwan ni wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ìròyìn ní Yahaya ló ránṣẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì láti wá fipá bá arábìnrin náà lòpọ̀ nígbà tó wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ̀.

Adajo Akinpelu sọ àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún fẹ́sùn ìfipábánilòpọ̀ àti ẹ̀wọ̀n ọdún méjì mìíràn fẹ́sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti fi hu ìwà àìda.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ́rùn lọ́nà àádọ́ta náírà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

Adájọ́ ní fúnra àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ àti pé sísọ wí pé arábìnrin tí wọ́n bá lòpọ̀ náà jẹ àwọn lówó jẹ́ ọ̀nà láti fẹ́ sá fún ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ náà, olùpẹjọ́, Muslimat Suleiman láti iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Kwara ní ìdájọ́ náà dùn mọ́ àwọn pé àwọn afúrasí náà kojú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ọwọ́ Ọlọ́pàá Kwara tẹ àwọn afurasí tó ń ṣọṣẹ́ lágbègbè Isin

Kwara kidneppers

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Kwara ti nawọ gan awọn afura si odaran ajinigbe kan, won si ti se afihan wọn niluu Ilọrin.

Awon afurasi yii a gbọ pe awọn lo n sọse ni ijọba ipinlẹ Isin, ni ipinlẹ Kwara.

Lara awọn ohun ija oloro ti ọlọpaa ka mọ won lọwọ ti wọn si ti gba gẹgẹ bii ẹri ni ada panapana marun un ati oogun ibilẹ bii olohunde.

Ọlọpaa tun ka oniruru ẹrọ ilẹwọ lọwọ wọn, to fi mọ ibọn ilewọ ati ọta ibọn ọhun.

Atẹjade lati ọọfisi ọlọpaa niluu Ilorin sọ pe nnkan bii aago marun irọlẹ ni awọn afurasi naa kọlu awọn ọkunrin meji kan ti wọn n rinrinajo ninu ayọkẹlẹ Camry kan.

Kwaa kidnappaers

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Ọlọpaa ni awọn ọkunrin meji ọhun, Abubakar Haruna ti apẹle rẹ n jẹ ‘Muslim’ ati Kayode Musa n rin irinajo lati Ilu Oke-Onigbin lọ si ilu Isanlu-Isin ki awọn afurasi naa to kọlu wọn.

Atẹjade ọhu ni “Ṣadede ni awọn agbebọn kan jade, ti igbagbọ wa pe wọn jẹ Bororo Fulani yọ si wọn lati inu igbo, ti wọn si ji awọn mejeji gbe, wọn si parẹ pada si inu igbo.

“Bi iwadi ṣe n lọ lọwọ lati wa awọn ajinigbe naa ri, ni nkan bi ago mefa abọ ni wọn doju ibọn kọ awọn ọlọpaa, fijilante ati awọn ọdẹ, ti awọn naa si n da pada si wọn.”

A gbọ pe awọn afurasi naa yin’bọn pa meji ninu awọn to wa ni akaso wọn, ti wọn si na papa bora pelu ọpọlọpọ ọgbẹ ibọn lara awọn miran lara won.

Awọn ọlọpa, fijilante ati ọdẹ naa yabo igbo to wa laarin Ijara-Isin ati Isanlu-Isin, ti wọn woye pe wọn sa pamo si.

Nibẹ ni wọn si nawọ gan wọn pelu awọn ohun ija oloro ti wọn kan mọ wọn lọwọ.