Ẹgbẹ́ awakọ̀ èèrò nípìnlẹ̀ Eko kéde àdínkù 25% sí owó ọkọ̀ àti tíkẹ́ẹ̀tì tí àwọn awakọ̀ n já 

Musiliu Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Facebook

Alaga àjọ to n mojuto awọn ibudokọ èrò nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya (MC Oluomo), ti kede awọn nnkan amayedẹrun lati dín irora subsidy ti ìjọba Naijiria fi opin si.

Nibi ipade kan ti Ọgbẹni Akinsanya ṣe pẹlu awọn ọmọ igbimọ oludari rẹ lo ti kede pe èrò ati awọn awakọ̀ ni àwọn nnkan amayedẹrun naa kàn.

Ikede naa waye nibi ipade àwọn adari ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èrò ati awọn awakọ̀, ni olu ile ẹgbẹ́ naa to wa ni agbegbe Oko Oba, Agege, nipinlẹ Eko lọjọ Ìṣẹ́gun, ọjọ kini, oṣù Kẹjọ.

Nibi ipade naa, ẹgbẹ́ awakọ̀ fẹnuko pe:

Tikẹẹti ti àwọn awakọ n gbà ni N800 yoo dinku si N600.

Fun awọn èrò, ibi ti ọkọ̀ n gbe ni N500 ti dinku si N300. Ibi ti ọkọ n gbe ni N200 ti di N150.

Fun awọn to n wa kẹ̀kẹ́ Marwa, ati awọn ọlọkada, àdínkù ìdá marundinlọgbọn yoo bá iye ti wọn n ra awọn tikẹẹti ẹgbẹ́ awakọ̀.

Lati mu ki òfin tuntun yii múlẹ̀, Ọgbẹni Akinsanya ṣàlàyé pe igbimọ alamojuto ti wa lati rii dájú pe awọn awakọ ati àwọn to n ta tikẹẹti tẹle ofin tuntun ẹgbẹ́.

Àwọn ọmọ igbimọ oludari ẹgbẹ́ nipinlẹ naa, to fi mọ awọn alaga garaaji ọkọ̀ kọ̀ọ̀kan, ati awọn adari ẹgbẹ́ ti igbimọ bá yàn, ni yoo ma a dari igbimọ alamojuto ọ̀hún.

Musiliu Akinsanya sọ pe “ẹgbẹ́ awakọ yoo ṣe gbogbo nnkan to ba le ṣe lati má jẹ̀ ẹ́ kí ara ni aráàlú.”

Yatọ si adinku owo ọkọ, ajọ tun kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ ko nii darapọ mọ iwọde tabi iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ni Ọjọ́rú.

O ni àwọn ṣe ìpinnu naa nitori pe ijọba ipinlẹ Eko pese ayika to wa ni alaafia fun awọn lati maa ṣiṣẹ́.

” Nitori naa, ko si ìdí kankan fun wa lati kopa ninu ìyanṣẹ́lódì to le da alaafia ipinlẹ yii rú.”

Ọjọ Ajé ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, kede adinku ìdá àádọ́ta si owo ọkọ̀ èèrò to jẹ ti ìjọba. Bákan naa lo kede pe ki ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èèrò ti kii ṣe ti ijọba ṣe adinku ìdá marundinlọgbọn, lati mu ìtura ba araalu.

Ọṣẹ to kọja ni ẹgbẹ́ NLC ati TUC kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ naa yoo bẹrẹ ìyanṣẹ́lódì ati ìwọ́de, lọjọ keji, oṣu Kẹjọ.

Wọ́n ni igbésẹ̀ yii jẹ dandan nitori bi ọ̀wọ́n gógó ṣe ba gbogbo nǹkan ni ọjà, ati ìṣòro ti awọn ọmọ Naijiria n koju, nitori awọn ijọba tuntun n gbé.