Àwọn agbébọn tún jí àlùfáà ìjọ Kátólíkì míràn gbé ní Kaduna

Eeyan kan ti wọn di lọwọ sẹyin

Oríṣun àwòrán, other

Awọn agbebọn tun ti ji alufa ijọ Aguda kan gbe nipinlẹ Kaduna.

Gẹgẹbi iroyin to ṣẹṣẹ lu sita, ni ijọba ibilẹ Kauru ni wọn ti ji alufa, Emmanuel Silas gbe ni ayika ijọ to ti n ṣiṣẹ, ijọ Aguda Saint Charles Catholic Church, Zambina lowurọ ọjọ Aje.

Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọsẹ meji ti awọn agbebọn kan pa alufa ijọ Aguda to wa ni iṣakoso ijọ aguda ni ile ẹkọ giga gbogboniṣe Kaduna Polytechnic, Ẹniọwọ Vitus Borogo ni oko rẹ ni Kujama, nijọba ibilẹ Chikun.

Awọn ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn giwa daosisi ijọ aguda lẹkun Kafanchan, Ẹniọwọ Emmanuel Okolo fi idi iṣẹlẹ yii mulẹ pẹlu alaye pe aifarahan alufa naa fun isin adura owurọ lọjọ Aje lo jẹ ki wọn tete mọ ohun to ṣẹlẹ.

Alufa Emmanuel ko ṣai tun sọ pẹlu idaniloju pe awọn yoo lo gbogbo ọna to ba tọ labẹ ofin lati rii pe wọn tu alufa naa silẹ.

Bakannaa lawọn agbebọn tun ji alufa ijọ Aguda meji gbe ni ipinlẹ Edo lopopona marosẹ Benin si Auchi.

Aworan ọwọ eeyan kan ti wọn fi okun so

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Edo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe Ẹniọwọ Udo Peter  ti ijọ aguda St. Patrick’s Catholic Church nilu Uromi ati Philemon Oboh ti ijọ aguda ti ijọ St. Joseph Retreat Center, nilu Ugboha gẹgẹ bi awọn alufa mejeeji ti wọn ji gbe.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni ọjọ Abamẹta to kọja ni iṣẹlẹ tipinlẹ Edo naa waye.