A dúpé àjàkálẹ̀ aàrùn Ebola ti dópin ní DR Congo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti kede pe ajakalẹ aarun Ebola ti dopin lorilẹede DR Congo.

Eyi ko ṣẹyin ajakalẹ aarun naa to be silẹ laarin oṣu mẹta ni orilẹede ọhun.

Ajọ WHO ninu atẹjade gba ọwọ adari Ajọ naa ni Afrika, Dokita Matshidiso Moeti ni bi wọn ṣe tete koju rẹ ni waranṣẹṣa lo jẹki o tete dopin.

Eniyan mẹrin lo ti ku lasiko ti ajakalẹ aarun naa bẹ silẹ ni igba kẹrila lati ọdun 1976 ti o ti n ba wọn finra.

Lara awọn mẹta to ku naa ni wọn fi idi rẹ mulẹ pe ajakalẹ aarun Ebola lo gbẹmi wọn, ti wọn si ṣapejuwe ikẹrin gẹgẹ bi eleyii to  ṣeeṣe ko niiṣe pẹlu aarun naa.

Ajọ WHO ni awọn yoo tẹsiwaju lati ma sayẹwo aarun na bo ba ṣe n lọ.

Bakan naa ni wọn gboriyin fun ijọba orilẹede Congo fun bi wọn jọ ṣe ṣiṣẹ pọ lati gbogun ti aarun naa to si wọle naa.

Wọn ni eleyii fihan pe bibori aarun ki aarun niṣe pẹlu igbaradi, fifi iye si bi o ṣe n lọ ati ṣiṣe bo se yẹ ni asiko lai wẹyin.