Copenhagen Shootings: Kí ló lè mú ọmọ ọdún 22 gbébọn lọ ilé ìtajà lọ pànìyàn?

Aworan agbebọn to n yan ka ile itaja to ti pa eeyan

Oríṣun àwòrán, MAHDI AL WAZNI

Eyan mẹta ti padanu ẹmi wọn ti awọn mẹrin mii si farapa nigba ti agbebọn kan se ikọlu si ile itaja igbalode kan ni olu ilu orileede Denmark,Copenhagen.

Awọ́n ọlọpaa ni awọn meji ninu awọn to ku yi jẹ ọmọ orileede Denmark ti wọn si jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

Ọmọ Russia kan ti ọjọ ori tiẹ naa jẹ ọdun mẹtadinladọta naa padanu ẹmi rẹ.

Awọn ọmọ ilẹ Denmark meji kan ati ọmọ Sweden meji mii wa ninu ewu ni ile iwosan.

Arakunrin ẹni ọdun mejilelogun ọmọ ilẹ Denmark kan ti wọn mu lori iṣẹlẹ yi la gbọ pe o ni arun ọpọlọ.

Ọga ọlọpaa Soeren Thomassen lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Wọn ko ti darukọ afurasi yi a si gbọ pe yoo koju adajọ lati dahun ibeere lọjọ Aje.

Olootu ijọba Denmark, Mette Frederiksen sọ pe ikọlu nla ni eleyi ti Denmark koju yi.

O loun fẹ gba awọn ọmọ orileede naa niyanju pe ki wọn gbaruku ti ara wọn lasiko inira yi.

”Orileede wa to rẹwa to si kun fun alaafia ti ri iyipada laarin iṣẹju aaya.”

Ikọlu si ile itaja igbalode yi waye gẹgẹ bi Denmark ṣe n yayọ pe awọn gba alejo abala ikẹta akọkọ idije kẹkẹ wiwa Tour de France .

Aworan ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye
aworan awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọpọ eeyan lo ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi.

Lọdun 2015 ni iru iṣẹlẹ yi waye kẹyin ni Denmark.

Nigba naa lọhun, eeyan meji padanu ẹmi wọn ti awọn ọlọpaa mẹfa si farapa nigba ti ikọlu ṣẹlẹ si ile ijọsin synagogue kan ati ibudo aṣa kan nibẹ.

Wọn pada ri agbebọn naa pa nigba to doju ija kọ awọn ọlọpaa.

Denmark jẹ orileede to ni ofin to le nipa rira ibọn.

Wọn ko faaye gba pe ki eeyan maa gbe ibọn kaakiri nita.