Amẹ́ríkà já bàlúù aṣòfófó China lórí òkun Atlantic

Aarẹ Xi jin Pin ti China ati Aarẹ Joe Biden ti Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Reuters

Orilẹede Amẹrika ti ja baluu alafẹfẹ (baloon) orilẹede China kan, ti wọn kẹfin pe o n ṣe iṣẹ alami lori awọn ibudo ologun pataki-pataki lorilẹede naa.

Ileeṣẹ ọrọ aabo ilẹ Amẹrika fi idi rẹ mulẹ pe lori agbami ilẹ naa ni wọn ti ja baluu alafẹfẹ naa bọ silẹ.

Ileeṣẹ ọrọ okeere lorilẹede China, ti fi aidunu orilẹede naa han lori bi Amẹrika ṣe ja a bọ.

Awọn fidio kaakiri awọn ileeṣẹ mọhunmaworan lorilẹede Amẹrika fihan bi baluu alafẹfẹ naa ṣe n jabọ si inu okun lẹyin ti o bu gbamu.

“Awọn ologun n wa awọn afọku baluu afẹfẹ naa pẹlu ọkọ ogun oju omi meji”

Baluu ijagun F-22 jet fighter ni wọn fi ja baluu alafẹfẹ naa bọ.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọrọ abo lorilẹede Amẹrika ṣalaye fun awọn ileeṣẹ iroyin nilẹ Amẹrika pe inu okun nitosi etikun Myrtle ni South Carolina lo ja si.

Awọn ologun ti n wa awọn afọku baluu afẹfẹ naa pẹlu ọkọ ogun oju omi meji lagbegbe naa.

Aworan bi wọn ṣe ja baluu alafẹfẹ naa balẹ

A lanfani lati ṣe agbeyẹwo gbogbo ohun elo to wa lara baluu afẹfẹ naa eyi to si ti ṣe anfani nla fun wa – Amẹrika

Atẹjade kan lati ileeṣẹ ọmọogun Amẹrika fisita ṣalaye pe gbogbo eto to yẹ lati daabo bo gbogbo awọn ibudo ologun rẹ, ki baluu afẹfẹ alami naa ma baa ri ohunkohun ko jọ fun orilẹede China, lawọn ti se.

A si ti ri awọn eroja to wa ninu baalu naa gẹgẹ bi ohun to wulo fun iwadii nla fun wọn.

“A lanfani lati ṣe agbeyẹwo gbogbo ohun elo to wa lara baluu afẹfẹ naa eyi to si ti ṣe anfani nla fun wa.”

Lati Ọjọbọ ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto abo orilẹede Amẹrika ti kẹẹfin baaluu naa ni ipe ti n jade si aarẹ Joe Biden lati ja a bọ.

Lẹyin ti wọn ja baluu afẹfẹ naa bọ ni Aarẹ Biden sọ pe “Wọn ja a bọ laisi wahala kankan, mo si fẹ ki awọn ọmọogun ofurufu wa to ṣe iṣẹ naa.”

Akawe lori baluu naa

Baalu wa sina wọ Amẹrika ni, ko si awakọ ninu baalu naa, o kan sina ni – China

Ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin wakati diẹ, ileeṣẹ ọrọ okeere ni China sọ pe: “Orilẹede China ti sọ fun Amẹrika laimọye igba lẹyin ti iwadi fidi rẹ mulẹ pe baluu naa kii ṣe ti ologun ati pe o kan ṣina wọ ilẹ Amẹrika ni nitori pe ko si eeyan to n wa a- aṣiṣe lasan ni.”

Ọrọ ọhun ti wu dukuu silẹ laarin orilẹede mejeeji yii pẹlu bi minisita fọrọ okeere ni Amẹrika, Antony Blinken ṣe tete wọgile abẹwo to fẹ ṣe si orilẹede China lopin ọsẹ yii tẹlẹ, lẹyin to pe iṣẹlẹ naa ni “ iwa ti ko boju mu.”

Awọn alaṣẹ orilẹede China ti sẹ kanlẹ pe iṣe alami ni baluu alafẹfẹ naa n ṣe. Wọn ni baluu ti wọn fi n ṣe iwadii oju ọjọ ni ki o to ṣina nipasẹ afẹfẹ.