“Vandi bèèrè ọ̀tá ìbọn mìíràn lọ́wọ́ mi torí ọta ìbọn rẹ̀ kó pé mọ́ lẹ́yìn ikú Bolanle Raheem”

Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan lara awọn Ọlọpa to n jẹri nibi igbẹjọ to n sawari iku to pa agbẹjọro kan nilu Eko, Bolanle Raheem, ti jẹri nile ẹjọ, nipa awọn iṣẹlẹ to waye pẹlu rẹ ati afurasi ọlọpa ti wọn fẹsun iku obinrin naa kan, Vandi Drambi.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ ọdun keresimesi to kọja ni wọn yinbọn mọ Raheem Bolanle to loyun sinu, ti wn si fi ẹsun ipaniyan naa kan ọlọpa Drambi Vandi, to ṣiṣẹ ni agọ ọlọpa to wa ni Ajiwe lagbegbe Ajah nipinlẹ Eko.

Insipẹkitọ Sunday Akagu, nigba to n jẹri nile ẹjọ lori igbejọ Vandi salaye pe lẹyin iṣẹlẹ naa, Drambi Vandi beere ọta ibọn lọwọ oun.

O ni Vandi sọ pe oun fẹ fi ọta ibọn to n beere naa sinu ibọn oun nitori awọn ọta ibọn to ṣẹku lọwọ rẹ ti din.

“Vandi kọ lati salaye ohun to sẹlẹ fun mi lẹyin iku Bolanle Raheem”

Sunday, ẹni to ti n ṣe iṣẹ ọlọpa fun ogun ọdun, ni oun kọ jalẹ lati fun Vandi ni ọta to beere naa.

Nigba ti adajọ agba fun ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo beere boya o fun Vandi ni ọta ìbọn to beere fun, Sunday ni rara oo, laelae, oun ko fun.

Ninu ijẹri rẹ, Sunday ni oun ati awọn akẹgbẹ oun mẹta lawọn n jọ ṣiṣẹ, ki DPO agọ ọlọpa Ajiwe to pe awọn nipe ojiji.

Lọgan ti awọn de ile iṣẹ ọlọpa Ajiwe, ile iwosan Budo, nibi ti wọn gbe oku Bolanle Raheem si, ni awọn lọ, nibẹ si ni oun ti pade Vandi.

Sunday ni oun beere ohun to ṣẹlẹ ṣugbọn Vandi kọ lati ṣalaye ayafi ti awọn baa de ọfiisi.

O ni DPO Ajiwe lo paṣẹ ki awọn gbe Vandi wa si agọ ọlọpa amọ Sunday ko sọ boya ibọn ṣi wa lọwọ Vandi nigbati wọn mú lo si ilé iṣẹ ọlọpa Ajiwe.

Nigba ti ile ẹjọ beere nọmba ara ibọn ti Vandi gbe lọwọ, Sunday ni oun ko ranti ayafi ti wọn ba yẹ iwe akọsilẹ ile iṣẹ ọlọpa wo.

‘Ìwádìí wa ti tú àṣírí Ọ́ọ́físà tó yìnbọn bá Bolanle Raheem’

Insipẹkitọ Olagunju Olatunji ni ẹlẹrii keji nile ẹjọ to tun fara han nile ẹjọ, to si sọ pe oun ni ọlọpaa to n tọpinpin ẹsun naa, ki wọn tilẹ to gbe e lọ siwaju ẹka to n ṣewadii ọtẹlẹmuyẹ, SCID.

O kẹnu bọ ọrọ lẹkunrẹrẹ lori ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti wọn gba iroyin pe wọn fẹsun kan ọfisa kan pe o yinbọn pa eeyan ni Ajah.

“Ọta ibọn dawati ninu ibọn rẹ lẹyin iṣẹlẹ naa”

Ọfisa Olatunji sọ fun ile ẹjọ pe “mo wa ninu agọ ọlọpaa ni ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Kejila to kọja yẹn ni nnkan bii ago kan ọsan ti arabinrin kan Enema Titilayo sare wọ agọ wa lati fi ẹjọ iṣẹlẹ naa sun.

A ke si igbakeji ọga wa DPO. Ati emi ati DPO atawọn mii lọ si ileewosan ti wọn gbe arabinrin naa lọ.”

Ile iwosan naa dari wọn lọ awọn ileewosan mii kaakiri, ibi ti wọn lọ kẹyin si ni wọn ti kede fun wọn pe Bolanle Raheem ti jẹ Ọlọrun nipe.

O fi kun un pe oun ri afurasi to n jẹjọ lọwọ ni ileewosan naa to n pa gulọ gulọ sapamọ labẹ atẹgun ibẹ.

“A ṣe iwadii iṣẹlẹ naa, afurasi sọ tẹnu rẹ, olupẹjọ naa ṣalaye ọrọ tirẹ a si lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye”, eyi ni alaye rẹ.

Nigbati agbẹjọro ijọba to jẹ agbẹjọro agba ipinlẹ Eko beere pe ki ni iwadii wọn fihan ki wọn to gbe ẹjọ naa kuro ni agọ wọn…

Ohun ti iwadii awọn Ọlọpaa fihan

Ile ẹjọ

Olatunji ṣalaye pe “iwadii wa fihan pe olujẹjọ lo yinbọn lootọ eyi to pa arabinrin ọhun”.

Nigba ti wọn bii lere boya o mọ olujẹjọ ṣaaju iṣẹlẹ naa, o dahun pe “mo mọ olujẹjọ gẹgẹ bi ọkan lara ikọ wa, mi o fibẹẹ mọ pupọ nipa rẹ toripe wọn ṣẹṣẹ gbe mi wa si agọ wa ninu Oṣu Kọkanla ni.”

Lasiko ti wọn tun ṣe awọn ayẹwo mii, agbẹjọro olujẹjọ, Adetokunbo Odutola bii leere boya o wa nibẹ lasiko ti iṣẹlẹ yii waye, o dahun pe rara.

Nipa iye ibọn to wa fun iṣẹ lọjọ naa, Olatunji ni ọfisa meji pere lo fi orukọ silẹ lati lo ibọn lọjọ naa, Insipẹkitọ Vandi ati ọfisa mii, “nigba ti iṣẹlẹ naa waye taa si wo ibọn wọn, ọta ibọn meji lo ti din ninu ibọn ọfisa Vandi nigba ti ti ọfisa keji ṣi pe sibẹ”.

O fi kun un pe nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ti awọn de ileewosa, oun ri Insipẹkitọ Vandi to n sapamọ sabẹ àtẹ̀gùn to si wọ aṣọ ara tẹ pẹlu ibọn lọwọ.

Nigba ti wọn bii pe kilode to ṣe sọ pe ọfisa naa lo pa arabinrin ọhun, o ni nigba to yinbọn ba obinrin naa, ọkọ rẹ sọkalẹ o si lọ di ọlọpaa naa mu titi to fi wọ ọ tẹle wọn lọ si ile iwosan.

Idi mii to sọ ni pe, ọfisa mẹta lo gba ibọn, ọta awọn meji to ku pe amọ ti Vandi nikan lo din meji.

Idi kẹta to sọ ni pe oun rii to n sa pamọ si abẹ àtẹ̀gùn ileewosan ti awọn ti lọ wo arabinrin naa.

Agbẹjọro olujẹjọ wa bii pe, ṣe yoo yaa lẹnu ti ọkọ ati aburo oloogbe naa ba ko ba sọ pe awọn rii ti olujẹjọ yinbọn, o ni bẹẹ ni yoo ya oun lẹnu.

Bakan naa ni Ọlọpaa mii jẹri nipa bi olujẹjọ ṣe n gbọn jinijini ti o n fi ibẹru ba awọn sọrọ lọjọ naa.

Adajọ ti sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹjọ Oṣu Keji.