Àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation tó pàgọ́ sí Alausa wọ gbaga ọlọ́pàá

Aworan awọn ajijagbara Yoruba nation naa ati Burẹdi ti wọn ka mọ wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, police lagos

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba lagbegbe Alausa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ pe awọn afurasi naa pa agọ kan si agbegbe Alausa ni nibiti ti wọn n gbero ati da iwọde silẹ.

“Loni, awọn ọmọ ẹgbẹ kan to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba bẹrẹ si ni pagọ si Alausa.

Wọn si gbero lati bẹrẹ iwọde alagbara kan lati ibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti tu agọ naa ka, wọn si fi panpẹ ofin mu awọn eeyan naa.

Iwadii ti bẹrẹ ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ SCID lori isẹlẹ yii.”

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Iwọde awọn ọmọ ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba kan waye ni oṣu kini ọdun yii ni agbegbe Ọjọta nilu Eko.

Afojusun iwọde naa ni lati tẹsiwaju pẹlu ijijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Iroyin sọ pe arakunrin kan ku lasiko iwọde naa lasiko ti awọn agbofinro atawọn oluwọde naa fija pẹẹta.