“Àlàyé rèé lórí bí a ṣé rí Ijoba Lande tó sọnù padà”

Aworan Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oye ti n la, ti ọrọ si ti n jade lori bi wọn se ri gbajumọ osere tiata ati adẹrinposonu nni ti wọn kede pe o di awati, Ijoba Lande pada.

Ọkan lara awọn ọrẹ alawada ori ayelujara naa, ti awọn mejeeji dijọ maa n se awada papọ, Alo Oluwatosin, ti ọpọ eeyan mọ si Ijesaekun lo sisọ loju isẹlẹ naa.

Ijesaekun lo gbe fọnran fidio kan soju opo ayẹlujara laarọ ọjọbọ lẹyin wakati diẹ ti wọn kede pe wọn ti ri Ijoba Lande.

Ninu fọnran naa ni Ijesaekun ti sọ pe awọn fijilante ni agbegbe Igango lo ri Ijọba Lande, ti wọn si tete da mọ pe alawada ti wọn lo sọnu ree.

Idi ree ti awọn ọdẹ fijilante naa se fun Ijoba Lande ni foonu lati pe awọn mọlẹbi rẹ pe ki wọn wa gbe oun.

Ijasaekun ati Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, Alo Oluwatosin Ijesaekun/Instagram

Ijoba Lande ko se ri rara nigba ti a ri, asọ ara rẹ ti dọti, yeepẹ wa lara rẹ, a si paarọ asọ fun – Ijasaekun

Ninu fọnran ọhun ni Ijasaekun ti se afihan bi asọ ijọba Lande se dọti, ti iyẹpẹ si wa ni gbogbo ara rẹ.

Ibẹ si ni wọn ti n gbọn awọn yeepẹ naa kuro ninu apo ati ara rẹ.

Ni abule ti wọn ti ri Lande yii si ni wọn ti bọ sokoto to dọti lara rẹ, ti wọn si wọ sokoto tuntun fun.

Fọnran ọhun tun se afihan bi Ijoba Lande ko se bọ bata si ẹsẹ, to si n sunkun bi ọmọde lasiko ti awọn ẹbi rẹ wa gbe.

Bakan naa ni wọn ko bata wa fun alawada naa lati sọ lọ sile rẹ.

Gẹgẹ bi Oluwatosin se sọ, ọkan lara awọn eeyan agbegbe lo ri Ijọba Lande nibi to wa lẹyin ti ri fọnran lori atelujara pe wọn wa osere tiata naa.

“Awọn fijilante lo fun ni foonu to fi pe iyawo rẹ

“Nigba ti a ri, iyẹpẹ si n da ni gbogbo ara rẹ, koda asọ rẹ dọti gidigan”

“A ni lati parọ asọ fun, ki a to gbe sori ayelujara nitori ko se ri rara lasiko ti a ri ijọba Lande

Fidio isalẹ yii ni Alo Oluwatosin gbe soju opo Instagram rẹ lati se afihan ibi ti wọn ti ri Ijọba Lande, ẹ tẹẹ lati wo o

Ìròyìn ayọ̀! Ìjọba Lande padà sílé pẹ̀lú omijé lójú

Aworan bi ijoba Lande se n wọ ile rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrinposọnu, Ganiyu Kehinde, ti ọpọ mọ si Ijọba Lande ni wọn ti sawari lẹyin to sa dede jade kuro nilẹ lọj́ọ Ìṣẹgun, ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2023.

Iyawo adẹrinposọnu ọhun lo ke gbajare sita lori ayelujara pe ọkọ oun ti di awati, ti ko si mu fọnu rẹ kuro ni ile.

Iroyin to n tẹ ileeṣẹ iroyin BBC News Yoruba lọwọ bayi ni pe pẹlu iranlọwọ awọn Alfa ati awọn mọlẹbi, Ijọba Lande ti pada si ilẹ.

Fidio kan to wa lori ayelujara llo safihan bi alawada ori ayelujara naa se pada sile.

Pẹlu omije loju lo fi wọ ile rẹ sugbọn a ko ti le sọ pato oun to mu sukun ati ohun to gbe kuro ni ile rẹ.

A maa mu iroyin wa fun yin lori rẹ bo ba se jẹ.

Fidio isalẹ yii ni Ijọba Lande gbe sori opo ayelujare rẹ, to si dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to fi ifẹ han si.

Gẹgẹ bi o se wa ninu fidio naa, Ijọba Lande ni ko wi ohunkohun sugbọn to bu si ẹkun kete to pada sinu ile rẹ lowurọ oni.

Òṣèré tíátà àti Aláwàdà ayélujára, Ijoba Lande, di àwátì, ìyàwó àtàwọn òṣèré tíátà figbe bọnu

Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, IJOBA LANDE/INSTAGRAM

Gbajúmọ̀ òṣèré tó tún jẹ́ adẹ́rìnínpòṣónú, Ganiyu Kehinde tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ijoba Lande ti di àwátì.

Ìyàwó Ijoba Lande ló ké gbàjarè sáwọn ọmọ Nàìjíríà nígbà tó fi fídíò kan sórí Instagram lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹta níbi tó ti ṣàlàyé pé láti alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni ọkọ òun ti kúrò nílé.

Ó ní láti alẹ́ ọjọ́ Àìkú tí ọkọ òun ti ṣinú tán ni òun ti gbúròó rẹ̀ kẹ́yìn tí òun kò sì ri kó padà sílé láti ìgbà tó ti jáde kúrò nílé.

Ijoba Lande

Oríṣun àwòrán, Ijoba Lande/Instagram

N kò mọ nǹkan tí mo le ṣe mọ́, gbogbo nǹkan ti sú mi láti ìgbà tí ọkọ mi ti di àwátì – Ìyàwó

Nínú fídíò náà ni ìyàwó rẹ̀ ti ń sunkún tó sì ní ọkọ òun ṣàdédé kúrò nílé láì mú fóònù rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tó ń jáde lọ.

Ó wá rọ ẹnikẹ́ni láti ran òun lọ́wọ́ tí wọ́n bá ní ìmọ̀ tàbí ti rí ọkọ òun ní ibikíbi kí wọ́n jọ̀ ọ́ jàre kàn sí òun nítorí òun kò mọ ibi tí òun le wá ọkọ òun sí mọ́.

Ó ṣàlàyé pé àgọ́ ọlọ́pàá tí àwọn ti lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí ni òun wà lásìkò tí òun ń ṣe fídíò náà tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí láti ṣe àwárí ọkọ rẹ̀.

Ó ní òun kò mọ nǹkan tí òun le ṣe mọ́ nítorí gbogbo nǹkan ti sú òun láti ọjọ́ mẹ́ta tí ọkọ òun ti di àwátì.

Ó fi kun pé ẹnikẹ́ni tó bá mọ nǹkankan nípa bí àwọn ṣe le rí ọkọ òun le kàn sí òpó ayélujára Instagram nítorí fóònù rẹ̀ wà ní ọwọ́ òun nítorí ọkọ òun k]o mú fóònù rẹ̀ jáde nígbà tó ń lọ.

Ọ̀pọ̀ òṣèrẹ tíátà ń ké tantan lórí ayélujára pé níbo ní Ijoba Lande sọnù sí?

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti mú kí àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn ti máa kọ nǹkan nípa Ijoba Lande sórí Instagram láti fi kéde rẹ̀ pé ó ti di àwátì tí wọ́n sì ń bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn lórí bí yóó ṣe di rírí.

Nkechi Blessing lójú òpó Instagram rẹ̀ kọ wí pé tí ẹnikẹ́ni bá gbúròó Ijoba Lande ibikíbi, kí onítọ̀hún fi tó àgọ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní ìtòsí létí.

“Láti ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ló ti di àwátì, Ọlọ́run yóó bùnkún yín bí ẹ ṣe ń bá wa pín ìròyìn yìí,” Nkechi Blessing kọ sí ojú òpó rẹ̀.

Bákan náà ni gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Cute Abiola náà fi sójú òpó rẹ̀ pé àwọn kò mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lórí Ijoba Lande tó sì ń bèèrè pé ṣe ẹnikẹ́ni gbúròó rẹ̀ ní agbègbè wọn.

Ta ni Ijooba Lande?

Ganiyu Kehinde tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ijoba Lande jẹ́ gbajúmọ̀ aláwàdà lórí ayélujára Instagram àti Tiktok.

Èdè Yorùbá ni ó máa ń lò láti fi ṣe àwàdà lórí ayélujára lọ́pọ̀ ìgbà.

Ní ọdún 2019 ló di ìlú mọ̀ọ́ká lẹ́yìn àwọn fídíò àwàdà kan lọ káàkiri lórí ayélujára.

Òun ni ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ Otisumi tí ọ̀pọ̀ máa ń lò lórí ayélujára.

Ó máa ń kọrin tó sì tún máa ń ṣe eré sinimá pẹ̀lú.

Ní ọdún 2019 ló gbé fíìmù rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde tó pè ní Ijoba Lande.

Ó ní ìyàwó tó sì tún ti bí ọmọ pẹ̀lú.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí