DSS kéde ọ̀nà méjì táwọn olóṣèlú kan ń déte láti dojú ìjọba alágbádá bolẹ̀

Ileesͅeͅ oͅteͅleͅmuyeͅ ni Naijiria, DSS ti ni lootoͅ ni awoͅn kan n gbimoͅ pọ lati da alaafia orileͅede Naijiria ru nipa gbigbe ijoͅba fidieͅ kaleͅ.

Agbeͅnusoͅ fun ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, Peter Afunaya lo sisọ loju ọrọ yii loju opo Instagram woͅn pe awoͅn oloselu kan n gbimoͅ ika si orileͅede Naijiria.

Afunaya ni awoͅn yoo sa gbogbo ipa awoͅn lati gbogun ti eͅnikeͅni to ba gbimoͅ lati da rogbodiyan sileͅ ni Naijiria.

Bakan naa ni woͅn ni awoͅn ti sͅawari awoͅn oloselu kan ti woͅn n gbimoͅ lati gbe igbeseͅ yii ti woͅn si ni woͅn yoo fi oju wina ofin.

Awọn osisẹ DSS

Oríṣun àwòrán, DSS

“Gbogbo awoͅn to feͅ diteͅ gba ijoͅba nipa sise iwọde tako idibo gboͅdoͅ dakeͅ ni kiakia”

DSS tẹsiwaju pe ‘’A n kiloͅ fun eͅyin olosͅelu wi pe a ko ni gba yin laaye lati gbe iroyin eͅleͅjeͅ tabi gbe igbeseͅ lati da rogbodiyan sileͅ ni Naijiria.’’

‘’A ri pe awoͅn kan n gbiyanju lati da wahala sileͅ ni Naijiria nipa sise ifeͅhonuhan alaini gbedeke, eleyii to le da wahala sileͅ ni Naijiria.’’

‘’Gbogbo awoͅn to feͅ diteͅ gba ijoͅba gboͅdoͅ dakeͅ ni kiakia, ki woͅn gbe jeͅ.’’

‘’Ohun ti a moͅ ni pe imoͅtara eͅni lo mu ki woͅn gbe iru igbeseͅ beͅeͅ, eyi ti yoo pa awoͅn araalu lara.’’

Bakan naa ni DSS ke si awoͅn araalu lati gba alaafia laaye, ki ireͅpoͅ le wa laarin awoͅn araalu ati ijoͅba.