Ìjọba Amerika gba $53m padà lọ́wọ́ Alison-Madueke àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile iṣẹ to wa eto idajọ lorilẹede Amerika ti kede idajọ wọn lori igbẹjọ meji to da lori lilu owo ilu ni ponpo lati fi ko ọrọ jọ.

Awọn owo naa ni wọn ni minisita fun ọrọ epo bẹntirol tẹlẹ, Diezani Allison-Madueke kojọ pẹlu awọn oṣiṣẹ rẹ, Kolawole Aluko ati Olajide Omokore

Awọn iwe ẹri lati ẹka eto idajọ fihan an pe awọn ile nla ti wọn ra si Amẹrika ko ṣẹyin owo Naijiria tawọn eeyan yii lu ni ponpo.

Lẹyin igbẹjọ naa ni adajọ ni awọn ti ri miliọnu mẹtalelaadọta dọla gba pada lẹyin ti wọn gba awọn ohun ini wọn to fi mọ miliọnu mẹrindinlogun miran.

Gẹgẹ bi iwe igbẹjọ naa ṣe sọ, lati ọdun 2011 si 2015 ni Aluko ati Omokore ti lẹdi pọ lati san riba fun Diezani to jẹ adari ẹka epo rọọbi ni Naijiria nigba naa.

Lẹyin naa ni Diezani lo ipo rẹ lati fi gba iṣẹ akanṣe fun ileeṣẹ Aluko ati Omokore.

Wọn si lo owo naa lati fi ra awọn ohun ini bii ile nla ni California, New York, Galactia Star

Awọn owo to jade lati owo riba ti wọn gba naa ati awọn iṣẹ akanṣe naa lo le ni ọgọrun un miliọnu dola.

Wọn si lo owo naa lati fi ra awọn ohun ini bii ile nla ni California, New York, Galactia Star, ọkọ oju omi ati awọn ohun ini miran pẹlu ileeṣẹ Shell.

Bakan naa ni Aluko lo awọn ohun ini yii lati fi ya owo lọwọ ileeṣẹ epo rọọbi Shell. Amọ ileeṣẹ eto idajọ naa ti da awọn owo ti wọn ya naa pada.

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI International Corruption Squad ni Washington, IRS-CI ati FBI Los Angeles lo ṣe iwadii ọtẹlẹmuyẹ naa.

Ẹ kan si wa tẹ ba mọ onijibiti to ko owo wa si Amẹrika – FBI

Ọdun 2015 ni wọn gbe ajọ naa kalẹ lati gbogun ti iwa ajẹbanu ni orilẹede naa.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun ajẹbanu kan ni awọn orilẹede miran to nii ṣe pẹlu Amẹrika.

Ajọ FBI wa kesi awọn araalu to ba mọ nipa owo ilu ti wọn lu ni jibiti lorilẹede Amẹrika tabi ti wọn n lo orilẹede naa lati ko owo pamọ, ki wọn kan si wọn ni ips.fbi.gov/ tabi ki wọn fi email ranṣẹ si [email protected].