Wo ìlànà méje tó de gbígba owóyàá akẹ́kọ̀ọ́ àti ìdápadà rẹ̀

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu abadofin eto ẹyawo fawọn akẹkọọ ọdun 2023.

Eleyi wa lara awọn ileri to ṣe lasiko to n polongo idibo.

Dele Alake agbẹnusọ aarẹ lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin nile ijọba lAbuja.

O ni eto yii labẹ akoso ileeṣẹ eto ẹkọ yoo seto ẹyawo fawọn akẹkọọ fasiti ti nkan ko gunrege fawọn ati obi wọn.

Aworan Aarẹ nibi to ti buwọlu abadofin eto ẹyawo ẹkọ

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN PRESIDENCY

Koko pataki meje to wa ninu ofin ẹyawo akẹkọọ:

Olori ile aṣojusofin tẹlẹ Femi Gbajabiamila lo ṣagbatẹru abadofin yi nigba to jẹ olori ile.

Awọn ti yoo ba jẹ anfaani ẹyawo yi yoo kopa ninu ayẹwo lati mọ boya wọn kaju oṣuwọn lati jẹ anfaani yi.

Awọn nkan amuyẹ ti wọn yoo yẹwo lara awọn to ba fẹ jẹ anfaani yi ni iwọn yi:

  • O gbọdọ jẹ akẹkọọ ni ile ẹkọ giga ni Naijiria
  • Ẹya eeyan ko ni nkankan ṣe pẹlu jijẹ anfaani ninu ẹyawo yi
  • Owo ile ẹkọ nikan ni ẹyawo yii wa fun, ko si fun ounjẹ jijẹ tabi nkan mii
  • Bo ba ṣe owo ti wa a fi se iṣẹ kan tabi omiran lo n wa, ko si anfaani ẹyawo yi fun ẹ.
  • Ipenija ara kankan ko jẹ idiwọ lati jẹ ninu anfaani yi
  • Awọn akẹkọọ to jẹ́ akẹkọọ ile ẹkọ giga aladani ko le jẹ anfaani yi
  • Ko si akẹkọọ ti ko le jẹ ninu anfaani yala ọkunrin obinrin, musulumi tabi Kristẹni.

Ilana méje to de sisan ẹyawo akẹkọọ pada fun ijọba:

Akọkọ ohun to yẹ ki a ṣalaye ni pe ẹyawo yi kii ṣe ipin rẹ ninu ogun Naijiria.

O di dandan lati san owo to ba ya fi kẹkọ pada.

Ofin to de ẹyawo yii ṣalaye ọna ti ijọba yoo fi gba owo yi pada kete to ba pari eto ẹkọ rẹ.

Gbogbo ilana yii wa ninu abadofin naa to fi mọ bi ijọba yoo ṣe ripe awọn to kajuẹ nikan ni wọn fun ni ẹyawo yi.

Awọn ilana mii to de sisan owo yi pada ree:

  • Ijọba yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to n ba ṣiṣẹ lati le yọ owo yii diẹ diẹ ninu owo oṣu to ba n gba.
  • Ẹnikẹni to ba gba owo yi gbọdọ bẹrẹ si ni daa pada bẹrẹ lati ọdun meji lẹyin to ba pari eto isinru NYSC
  • Ida mẹwaa ni wọn yoo maa yọ ninu owo oṣu rẹ
  • Bi o ba n da iṣẹ ara rẹ ṣe,ida mẹwaa ere rẹ ni wọn yoo yọ lati fi san owo yi pada.
  • Iwọ lo gbọdọ gbe owo yi lọ si banki lati lọ da pada diẹ diẹ ninu ere rẹ
  • Bi eeyan ba gba owo yi,kete to ba pe ọgọta ọjọ lẹyin to ri iṣẹ tabi to da ileeṣẹ ti ẹ kalẹ, o ni lati fi gbogbo iroyin aknati rẹ,orukọ ile ifowopamọ,adirẹsi rẹ ati awọn iroyin mii ṣọwọ
  • Bi o ba kọ lati san owo yi,ti wọn ba fi le mu ẹ labẹ ofin,o ṣeeṣe ki o fẹwọn ọdun meji jura tabi ko si san owo itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira tabi ko si jẹ mejeeji