Àlàyé rèé lórí bí akẹ́kọ̀ọ́ 18 ṣe jẹ oúnjẹ ìjọba dèrò ilé ìwòsàn l’Osun

Aworan gomina Adeleke atawọn akẹkọọ kan to n jẹun nileẹkọ

Oríṣun àwòrán, osun state government/others

Ko din ni akẹkọọ mejidinlogun to di ero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ ọfẹ ti ijọba pese fun wọn ni ilu Osogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Ọrọ di ipaya ati ariwo lọsan ọjọ Aje ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ St James Primary School, Owo-Ọpẹ lẹyin ti awọn akẹkọọ jẹ ounjẹ ọfẹ, O-meal ti ijọba ipinlẹ naa maa n pese fun awọn akẹkọọ lojojumọ.

Igba akẹkọọ lo wa ni ile ẹkọ St James B lagbegbe Owoọpẹ nilu Osogbo nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ. Mẹtalelọgọrun ninu wọn lo lẹtọ si ounjẹ ọfẹ ijọba naa gẹgẹ bii kilaasi wọn.

Mejidinlogun ninu wọn ni ounjẹ ọjọ Aje naa pa lara.

Obu ẹyin ni wọn ṣe fun awọn ọmọ wa – Awọn iya awọn akẹkọọ to dero ile iwosan.

Aworan olounjẹ kan to n bu ounjẹ fun awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, osun state government

Ninu fidio kan eyi to lọ lori ayelujara, o ṣafihan awọn mẹta ninu akẹkọọ to dero ile iwosan nipasẹ ounjẹ naa nibi ti wọn ri n fa omi si wọn lara.

Nigba ti wọn n ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ, ọkan lara awọn akẹkọọ naa ni irẹsi pẹlu ẹyin sise ni ounjẹ ijọba ti wọn gbe wa fun awọn lowurọ ọjọ Aje, bi wọn si ti ṣe jẹ ẹ tan ni wọn bẹrẹ si ni i ṣe igbọnsẹ pẹlu inu rirun.

Awọn iya awọn akẹkọọ naa tun ṣalaye ninu fidio naa pe awọn gbọ oorun obu ẹyin ti awọn ọmọ awọn jẹ nigba ti wọn pada dele lati ile ẹkọ lọjọ Aje.

Wọn ni bi awọn ọmọ wọn ṣe n pariwo inu rirun ni wọn n yagbẹ gbuuru, eyi to mu ki awọn kọminu lori irufẹ ounjẹ ti olounjẹ ti ijọba gba se fun wọn.

Bawo ni ọrọ ounjẹ ofẹ ‘O-meal’ ṣe jẹ ni ipinlẹ Ọṣun?

Aworan arẹgbẹṣọla atawọn olounjẹ O-meal kan

Oríṣun àwòrán, osun state government

Lasiko isejọba ijẹta ni ipinlẹ Ọṣun, iyẹn ijọba Rauf Arẹgbẹṣọla ni wọn ṣe agbekalẹ eto ounjẹ ofẹ fun awon akẹkọọ awon ipele kini de ikẹrin ileẹkọ alakọbẹrẹ nibẹ gẹgẹ bi ara ọna lati tu bọ ṣe koriya fun awọn obi lati maa mu ki awọn ọmọde to ti to ileẹkọ lọ o wa sileẹkọ.

Eto naa gbajumọ to bẹẹ nigba naa ti ijọba apapọ labẹ aarẹ Buhari pẹlu gba lati lo o lẹka apapọ, bẹẹni awọn ijọba to tẹlẹ Arẹgbẹṣọla pẹlu n tẹsiwaju pẹlu rẹ.

Ijọba ipinlẹ Ọṣun bẹrẹ iwadii

Aworan awọn olounjẹO-Meal kan

Oríṣun àwòrán, osun state government

Gomina ipinlẹ Ọsun, Asemọla Adeleke ti paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin and ilanilọyẹ faraalu, Kọlapọ Alimi fi sita ni awọn akẹkọọ naa ti gba itọju wọn si ti kuro ni ileewosan bayii.

Gomina Adeleke ti paṣẹ ki wọn dawọ eto ounjẹ ọfẹ O-meal duro nile ẹkọ naa titi di igba ti iwadii yoo fi pari.

“Bakan naa ni wọn ti ranṣẹ pe gbogbo awọn olounjẹ to n dana ounjẹ ijọba ‘O-meal’ fun ile ẹkọ naa at’awọn alakoso wọn fun ipade.”

Ijọba Adeleke ni lati dẹkun fifi ẹmi awọn akẹkọọ ta tẹtẹ – APC

Nibayii, ẹgbẹ oṣelu alatako ni ipinlẹ Ọṣun, APC ti paroko ikilọ si ijọba to wa lode bayii ni ipinlẹ naa labẹ iṣakoso gomina Ademọla Adeleke pe ko dẹkun fifi ẹmi awọn akẹkọọ ṣere pẹlu ọrọ ounjẹ ti awọn ọlọṣibi ti ijoba gba si ẹnu eto ounjẹ ọfẹ ‘O-Meal’ n se fun awọn akẹkọọ jẹ nileẹkọ.

Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Sooko Tajudeen Lawal fi sita nilu Osogbo,

O ni abajada iha ailakasi ti ijọba kọ si ọrọ akoso ipinlẹ naa lo jẹyọ pẹlu ounjẹ ti wọn n se fun awọn akẹkọọ naa.