Àjọ̀dún Lisabi Agbongbo Akala tọdún 2022 ti bẹ̀rẹ̀ ní Abeokuta

Lisabi Day 2022

Aláké gbá àwọn odò lamoran láti yàgò fún wíwà owó òjìji

Kabiyesi, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo, Aláké tí ilé Ẹ̀gbá tí gbá àwọn odò níyànjú láti yàgò fún ìwà janduku.

O rọ̀ wọ́n làti jawo kúrò nínú ọ̀nà eburu láti wá owó òjijì ati fifi ipa wa ọlà.

Lisabi Day 2022

Òní ni Aláké gba amoran yìí lásìkò tí ó ṣe ìwúre níbí òkúta olumo láti sayajo ọdún Lisabi Eelekaarundinlogoji irú ẹ ti o wáyé nílùú Abẹ́òkúta tí ń ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ ogún.

Aláké, lo tún jé olórí Ọba ní ìlù Egba ni wíwà owó lọ́nà eburu àti wíwú ìwà jagidijagan ni ó ń ṣokùnfà bí àwọn odò ṣe ń kú ikú òjijì láwùjo wá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ó fi kún pé ìwà ibaje yóò dinku tí àwọn odò bá lè tẹnpele mọ wíwú ìwà ọmọlúwàbí.

Ọba Gbadebo ni àwokose réré ni Lisabi jẹ fún àwọn odò láti lè tá ògo ìlú Ẹ̀gbá àti ilẹ̀ Yorùbá lapapo jí.

Ayẹyẹ Ayajo ọdún Lisabi ọdun yìí ni àwọn lekan lekan tí peju pèsè ṣe láti ṣe ìwúre lórí òkúta olumo , kíkọ orin ògo Ẹ̀gbá àti ṣíṣe àwọn onírúurú àfihàn àṣà ilẹ̀ Yorùbá míràn hàn.

Lisabi Day 2022

Lára àwọn ènìyàn jankanjankan tí wọ́n pèsè síbí ayéye Lisabi ọdún yìí ni a ti rí Ààrẹ Ona Kàkànfo ile Yorùbá, Ibà Gani Adams, Oba Agura tí Gbagura, Abdul Sabur Bakir.

Awon mii tun ni Olú tí ìlú itori, Ọba Akorede Abdlfatai Akamo, Balogun Ẹ̀gbá, Sikirulahi Atobatele àti àwọn jankan jankan mìíràn.

Lisabi Day 2022

Ayẹyẹ Ayajo Àjọ̀dún Lisabi, Eelekaarundinlogoji irú ẹ ti ọdún yìí tí bẹ̀rẹ̀ ni ìlú Ẹ̀gbá.

Àjọ̀dún Lisabi Agbongbo Akala tọdún 2022 ti bẹ̀rẹ̀ ní Abeokuta

Ni ilu Abẹ́òkúta tí ń ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ogún níbí tí àwọn ọmọ bíbí Ẹ̀gbá, Oba, ìjòyè tí màá ṣe ajoyo àṣà, àti isese wọ́n.

Lisabi Day 2022

Ayeye odun Lisabi yii wa láti fi ṣé ìrántí àwọn akọni wọn bí LISABI AGBONGBO AKALA, SODEKE pelu awon mii ti won ti ja fun ominira Egba ti won si ti teri gbaso.

Lisabi Day 2022

Koda, odun yii tun wa fun sisami àwọn òun isenbaye bí ÒKÚTA OLUMO àti àwọn nkan mèremère míràn.

Kini pataki ọdun naa?

Lara pataki ohun tí wọ́n fi ń sàmì ayẹyẹ náà ni wọ́n tí lọ sí orí òkúta Olumo lónìí tí ń ṣe ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nibe ni Kabiyesi Aláké tí ilé Ẹ̀gbá, Oba Adedotun Arẹwà Gbadebo Okunkenu kẹrin tí o tún ṣé olórí Ọba ní ekun Egba gba adura itesiwaju Egba kaakiri agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa lo ko àwọn ọmọ bíbí Ẹ̀gbá, ìjòyè àti ará lọ sí ọjà itoku láti lọ ṣe ìwúre àti kíkọ orin ògo Ẹ̀gbá.

Lisabi Day 2022