Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ

Eku

Oríṣun àwòrán, Others

Iba Lassa foju han nipinlẹ Ọyọ, o gbẹmi Dokita meji

L’Ọjọbọ ni ijọba ipinlẹ Ọyọ tun mẹnuba ipa ti o n sa lati dẹkun itankalẹ iba ọrẹrẹ, ‘Lassa Fever’ lẹyin ti wọn ṣe awari iṣẹlẹ akọkọ ninu oṣu kini ọdun 2022.

Atẹjade ti Kọmisonna fun eto ilera n’ipinlẹ Ọyọ, Dr. Bode Ladipo kọ eleyii ti o to awọn akoroyin lọwọ nilu Ibadan lo fi idi rẹ mulẹ.

Nibe lo ti so nipa awọn oṣiṣẹ eto ilera mẹrin ọtọọtọ lo lugbadi iba naa, ti o si da ẹmi dokita meji ati oṣiṣẹ ile iwosan kan legbodo toun ti gbogbo igbiyanju awọn akọṣẹmọṣẹ to n tọju wọn.

Kini Kọmisọ́nna eto ilera naa tun so?

O ṣe alaye pe ipinlẹ naa ṣe akọsilẹ onka mọkandinlogun iṣẹlẹ iba naa pẹlu alaye wi pe wọn ti fi awọn ohun elo itọju ilera ṣọwọ si awọn ibudo itọju lati dẹkun itankalẹ arun naa jakejado ipinlẹ Ọyọ.

Ladipo ṣe alaye siwaju si i pe ẹka eto ilera ti pakun amojuto ti wọn n ṣe ni ẹsẹkuku gẹgẹ bi o ṣe fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ẹni ti arun naa le kọlu ni yoo ni anfani si itọju ti o peye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbese wo lo yẹ lati gbe ti o ba kẹ́fín iba Lassa?

Komisonna wa ke si gbogbo ẹni ti o ba n ko firi apẹrẹ arun naa lati gbe igbese akin fun itoju.

O ni pe ki won sakiyesi apeere bi i iba, egbo ọna ọfun, ara riro, eebi, ikọ, aya didun, oju tabi ọrun ti o wu, inu rirun, ẹjẹ to n jade loju, eti, imu tabi ẹnu ati awọn iṣẹlẹ mii.

Ati pe ki wọ́n fi ara han ni ibudo eto ilera ti o ba sun mọ wọn julọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nomba wo lo maa pe?

Komisonna tun sọ pe ki wọn pe ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lori awọn nọmba yii:

08095394000 tabi 08095863000.

Kọmisonna fun eto ilera parọwa si awọn eeyan ipinlẹ naa lati yago fun eku, ounjẹ ti igbẹ tabi itọ eku ba ti bo si gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe imọtoto ayika wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ