Bàbá Adesola Adedeji, ọ̀kan lára àwọn afurasí méje ń fẹ́ rọ́pò ọmọ rẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke

Timothy Adegoke àti Ramon Adedoyin

Ile ejo giga nipinle Osun ti sun igbejo lori iku Timothy Adegoke si Ọjọ Aje ọsẹ to n bọ.

Adajo Adepele Ojo lo fi oro naa mulẹ pe igbejo yoo bere lati yanana ọ̀rọ̀ ati lati ri i daju pe idajo ododo yoo ni waye.

Kini o tun selẹ̀ nile ẹjọ́ lonii?

Bakan naa ni ọ̀kan lara awọn agbejoro olujejo, Okon Ita beere fun anfani pe ki Baba ọkan lara awọn olujẹ́jọ́ naa wa rọ́p[s omo rẹ̀ ninu igbejo naa.

O ni eyi yoo je ki baba naa lati maa jejo lọ lati Ie fun ọ̀kan lara awon afurasi meje naa ni anfani lati lo toju ara re.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tani Adesola Adedeji ti o ni ailera yii?

Oruko afurasi naa ni Adesola Adedeji.

Oun lo wa lenu ise lasiko ti oloogbe Timothy Adegoke foruko sile nile itura Hilton naa ni Ile Ife lọ́jọ́ naa.

Adesola Adedeji yii lo ya aworan iwe iforukọ silẹ̀ awọn alejo nile itura naa sori foonu rẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Eni ti Adajo pada sọ pe ki wọ́n so ibeere naa gbigba beeli rẹ̀ naa di ọjọ́ Ajé to n bọ̀ nitori pe ara rẹ ko ya.

Adajo Adepele Ojo wa sun igbejo ati gbigba beeli Adesola Adedeji si ojo Aje osẹ to n bọ.

Ile Ejo ni Osogbo

Ki lo sele nile ejo loni?

Rahmon Adedoyin àti àwọn afurasí mẹ́fà tó kù kò yọjú sílé ẹjọ́ lónìí sùgbọ́n ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀

Iroyin to n te wa lọ́wọ́ lati ile ejọ́ giga ni Oke Fia ni Ososgbo ni pe awon Adedoyin ko si nile ejọ́ ni owuro yii.

Akoroyin BBC Yoruba to wa nibe salaye pe wọ́n ko ri Oloye Rahmon Adedoyin ati awon mẹ́fà to ku ti wọ́n je afurasi rara nile ejo naa to wa ni Oke Fia nilu Osogbo ni ipinle Osun ni guusu Iwo oorun Naijiria.

Saaju ni Adajo Ojo ti so pe ki wọ́n lo fi awọn mejeeje pamọ́ si ahamọ́ ni ilu Ilesa ni ipinle Osun ni ana.

Kini yoo sele lonii lori ọ̀rọ̀ Timothy Adegoke?

Òní ní Adájọ́ Ojo sún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke sí lẹ́yìn ohun tó sẹlẹ̀ ní Osogbo lánàá.

Ile Ejo ni Osogbo

Òní ní Adájọ́ Ojo sún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke sí lẹ́yìn ohun tó sẹlẹ̀ ní Osogbo lánàá

Òní ni ìgbẹ́jọ́ Ramon Adedoyin àti àwọn afurasí mẹ́fà mìíràn lórí ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ilé Ifẹ̀ tó kú sí ilé ìtura Hilton, ń tẹ̀síwájú ní ilé gíga Oke fia, Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun.

Ramon Adedoyin tó ni ile ìtura Hilton, Ilé Ifẹ̀ àti àwọn afurasí mẹ́fa mìíràn ló ń kojú ẹ̀sùn sínsin òkú Timothy Adegoke lọ́nà àìtọ́.

Nigba tí àwọn mẹ́fa yóòkù Adedeji Adesola, Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderogba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem àti Adebayo Kunle ni wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìlẹ̀dí-àpò-pọ̀.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wa ní Abuja ni ìgbẹ́jọ́ náà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ kí Agbẹjọ́rò mọ̀lẹ́bí Timothy Adegoke, Femi Falana kọ̀wé ráńṣẹ́ sí ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá orílẹ̀ dè yìí, Usman Baba láti dá ẹjọ́ náà padà sí ìpínlẹ̀ Osun.

Falana ní ó pọn dandan láti da ẹjọ́ náà padà sí Osun nítorí níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.

Lánàá ní ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ gíga Oke fia, ìlú Osogbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kí ló sẹlẹ̀ ní ilé ẹjọ́ lánàá?

Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun lánàá, Adájọ́ Adepele Ojo ní kí wọ́n fi Rahman Adedoyin àti àwọn mẹfa mii tí wọ́n jọ ń jẹ́jọ́ si ahamọ lori iku Timothy Adegoke.

Lẹ́yìn tí àwọn afurasí naa sọ fun Ilé ẹjọ́ pe awọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan nínú ẹ̀sùn mọ́kànlá tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹjọ́rò fún àwọn afurasí náà, Kunle Adegoke ati K. Eleja bèrè fún àǹfàní fún àwọn afurasí láti máa jẹ́jọ́ láti ilé wọn ṣùgbọ́n àwọn olùpẹjọ́ fárígá sí ìpè náà.

Adájọ́ Adepele Ojo wá sún ìgbẹ́jọ́ náà sí òní lẹ́yìn tí àwọn afurasí mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ ètò ìlera wọn.