Agbófinró, Agbẹjọ́rò àti Olóṣèlú balẹ̀ sílé ẹjọ́ láti mọ ẹni tí ìdájọ́ yóó gbè láàrin Adeleke àti Oyetola

Bí Tribunal ṣe ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ Adeleke àti Oyetola, ilé ẹjọ́ ti kún fọ́fọ́

Aworan

Ọpọ awọn eeyan lo ti ya bo ileẹjọ giga ipinlẹ lati gbọ idajọ lori ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu APC fi kan gomina Ademole Adeleke pe idibo to gbe wọle ko tẹle ilana to ba ofin mu.

Ẹgbẹ oṣelu APC lo pe ijawe olubori Gómìnà Ademọla Adeleke nibi eto idibo gomina ọjọ́ Kẹrindinlogun oṣu Keje, ọdun 2022 lẹjọ.

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye ati awijare awọn agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu mejeeji, oni ọjọ Kẹtadinlọgọn oṣu kinni ọdun 2023 ni ileẹjọ yoo gbe idajọ rẹ kalẹ.

Bawo ni nkan ṣe lọ lọwọ?

Aworan
Aworan

Ọpọ awọn ololufe ẹgbẹ oṣelu mejeeji ni wọn ti balẹ si ileẹjọ niluu Osogbo, ti awọn agbofinro ati awọn ẹsọ alaabo miiran si wa nibẹ lati ri pe idajo naa lọ ni irọwọrọsẹ.

Bakan naa ni awọn agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu mejeeji naa ti kalẹ, ti wọn si reti Adajọ

Fọran lori ẹrọ ayelujara BBC News Yoruba lori Faceback fihan pe ọpọ ariyanjiyan lo lọ lọwọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu mejeeji ati awọn Ọlọpaa.

Iwadii fihan pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni fun ẹnikẹni ti ko ba lẹtọ lati a ni ileẹjọ ni anfani lati wọle si ninu ileẹjọ.

Eyi ni ko dun mọ ọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ninu, ti wọn si bẹrẹ si ni tahun si arawọn.

Ti a ko ba gbagbe, ninu oṣu Keje ọdun 2022 ni ajo eleto idibo (INEC) kede Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina pẹlu ibo 403, 271 ti ibo Gboyega si jẹ 375, 027.