Dibu Ojerinde lò mí láti kó N5.2bn owó ìjọba ṣàpó ara rẹ̀ – Ẹlẹ́rìí sọ fún iléẹjọ́

Àjọ ICPC tun gbé ọ̀gá àgbà JAMB tẹ́lẹ̀, Dibu Ojerinde láti fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Jamb

Jimoh Olabisi, tii se igbakeji oludari tẹlẹ fun ajọ Jamb ti salaye fun ile ẹjọ pe ọga agba tẹlẹ fun ajọ naa, Dibu Ojerinde, lo oun lati kowo ijọba sapo.

Olabisi sọ eleyi ni Ọjọru, ọjọ kẹdogun, ọsu kinni ọdun 2023 nigba to farahan nile ẹjọ gẹgẹ bi ẹlẹrii ajọ ICPC nile ẹjọ giga niluu Abuja.

Ajọ ICPC wọ Ojerinde lọ ileẹjọ lojọ kẹfa oṣu keje ọdun 2021, pẹlu nọmba iwe ofin FHC/ABJ/CR/97/2021.

ICPC fi ẹsun mejidinlogun kan ọga agba JAMB naa lori pe o ṣe ṣe owo ilu mọkumọku lasiko to jẹ Ọga agba fun ajọ Jamb ati NECO.

Ojerinde sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun kankan, ti ile ẹjọ si gba beeli rẹ pẹlu igba milọnu naira.

Olabisi sọ pe oun lo n sakoso bi ẹka to n risi bi ajọ naa se si apo asunwọn owo si ile fowopamọ.

O fikun pe Ojerinde pasẹ fun oun lati lọ si ile ifowopamọ ni orukọ ajọ Jamb ati J.O Ojẹrinde ni ilefowopamọ kan.

O ni ninu ile ifowopamọ ti awọn si yii, ni owo n ijọba lọ, ti ko si lọ apo ijọba.

“Asẹ lati lọ si apo asunwọn owo nile ifowopamọ, iwe ti wọn fi ransẹ si banki naa ni Ojujẹjọ ati oludari ẹka to n risi owo ni ajọ naa, Mallam Umar Yakubu buwọlu pẹlu asẹ pe ki n jẹ alamojuto apo owo naa ni ile ifowopamọ.

“Mo salaye ninu ọrọ mi kan pe a si apo asunwọn banki naa lẹyin ti adehun waye laarin emi ati Ojerinde, lati maa ko owo ajọ NECO si ipamọ.

Ojerinde ni ileeṣẹ banki aladani, Osanta Microfinance Bank nigba to wa ni ẹnu isẹ ijọba

Olabisi ni Ojerinde ni ileeṣẹ banki aladani, Osanta Microfinance Bank nigba to wa ni ẹnu isẹ ijọba ati pe oun naa ni adari ni banki naa.

“Wọn fi mi si banki lati mu irọnu de ba bi wọn yo ṣe ma kowo ijọba wọle sinu banki naa.”

Ojerinde dèrò àtìmọ́lé àjọ ICPC fún ìgbàkejì

Wayi o, Ajọ ICPC ti kede pe oun ti gbe Ọga fun ajọ Jamb tẹlẹ, Ojọgbọn Adedibu Ojerinde.

Agbẹnusọ ICPC, Azuka Ogugua ni awọn gbe igbesẹ naa lọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 niluu Abuja.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi lede, wọn ni, “A mu Ọjọgbọn Ojerinde lori asẹ ile ẹjọ agba niluu Abuja.”

“Yoo ma koju awọn igbimọ to n ṣe iwadi lori awọn ẹri tuntun to jẹtọ lori ẹsun to ṣe ijẹjọ rẹ lọwọ pe o lu owo ilu ni ponpo lasiko to jẹ Ọga agba fun ajọ Jamb.

“Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ICPC sawari apo ilefowopamọ meji ni orukọ Trillium Learning Centre ati Sapati International School, to jẹ pe ibẹ ni owo ijọba bọ si.