Ìjà dópin, wo ọ̀nà tí òṣèré-bìnrin Yewande Adekoya àti ọkọ rẹ̀ gbà parí ìjà tó tú wọn ká

Yewande Adekoya ati ọkọ rẹ, Abiodun Thomas

Oríṣun àwòrán, Yewande Adekoye/Instagram

Yewande Adekoya ati  ọkọ rẹ, Abiodun Ishola tawọn mejeeji jẹ osere tiata lede Yoruba lo seṣee ki alafia ti pada sinu idile wọn.

Laipẹ yii ni Yewande gbadura fun ọgbọn lati mọ oun ti yoo ṣe bii ọkọ rẹ, Abiodun Ishola ṣe n tọrọ aforiji lọwọ rẹ ṣaaju ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, o ti to osu mẹjọ sẹyin ti ariwo ta lori ayelujara pe igbeyawo naa ti tuka, ti tọkọ-taya naa si ti n gbe lọtọọtọ.

Iroyin naa lo ba ọpọ ololufẹ awọn osere tiata mejeeji naa lojiji, ti wọn si fẹ mọ oun to ya wọn.

Bi ọkọ rẹ tiẹ n sọrọ lowelowe lori ayelujara amọ se ni Yewande n rawọ ẹbẹ sawọn ololufẹ rẹ pe oun ko fẹ ki wọn bu ọkọ oun.

Ọ ni oun ko fẹ ki ọrọ igbeyawo awọn di oun ti wọn yoo maa gba, bi ẹni gba igba ọti lori ayelujara.

Lati igba naa si ni koowa wọn ti n gbe lọtọọtọ, ti Yewande si n setọju ọmọbinrin meji to wa ninu igbeyawo naa.

YewandeAdekoya

Oríṣun àwòrán, Yewandeadekoyaabiodun/instagaram

Bawo ni ija tọkọ-taya se pari?

Mo si nifẹ rẹ, Yewande tọkantọkan, jọọ foju fo awọn iwa buruku ti mo hu siẹ sẹyin – Abiodun Thomas

Ọjọ kejilelogun osu kinni ọdun ni ọjọ ibi Yewand Adekoya, eyi to sami rẹ pẹlu aworan to rẹwa ldun yii.

Aworan naa si ni ọkọ rẹ lo, lati fi kede pe oun tọrọ aforijin lori awọn iwa to ti hu si lati ẹyin wa.

Nigba to n tọrọ aforiji naa, Abiodun Ishola Thomas ninu ohun to kọ si Yewande Adekoya lọjọ ibi rẹ ni:

“Ololufẹ mi nigba to n se ajọyọ ọjọ ibi rẹ, mọ fẹ fi asiko yii tọrọ aforiji fun awọn iwa aida ti mo ti hu sẹyin”.

Abiodun tẹsiwaju lati sọ wi pe oun nifẹ Yewande tokantokan, o si rọ lati foju fo awọn iwa buruku rẹ ki wọn le jọ gbẹ igbaye todara papọ.”

Mo nilo aforijin lati ọdọ rẹ, Ishola, ki ọkan mi to ti gbọgbẹ le ri iwosan – Yewande

Ninu esi rẹ,  Yewande ni oun ko mọ esi ti oun tiẹ le fun Abiodun.

O wa dupẹ lọwọ ọkọ rẹ pe oun mọ riri bo se tọrọ aforijin naa.

“Lootọ, mo nilo aforijin lati ọdọ rẹ, Ishola, ki ọkan mi to ti gbọgbẹ le ri iwosan.

Mo tẹwọ gba aforijin rẹ, ki Ọlọrun maa se amọna igbe aye wa.”

O wa tẹsiwaju lati tọrọ ọgbọn lọwọ Ọlọrun lati gbe igbe aye to dara.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Yewande Adekoya ti pinya pẹlu ọkọ rẹ, Ishola Abiodun lẹyin igbeyawo ọdun mẹjọ.

 Gẹẹ bi ọrọ rẹ, pẹlu bi o ṣe ni ifẹ ọkọ rẹ to , ti wọn si ti ni ọmọ meji, n ṣe ni ọkọ rẹ ma n sọrọ si lai naani rẹ gẹgẹbi obinrin.

Ọrọ ti Yewande kọ pada si ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Yewande Adekoya