Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀

Agbẹjọro to n ja nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Politics Nigeria

Sinima agbelewo kọ leleyii. O soju mi koro ni.

Ki ni nkan to ṣẹlẹ ti agbẹjọro méjì fí yọ ẹsẹ si arawọn niwaju adajọ majisreeti to si di ohun tàwọn eeyan n ṣe kayeefi si loju opo ayelujara ni Naijiria?

Gẹgẹ bi awọn ileesẹ iroyin Naijiria kan ṣe sọ, John Yuwa Esq ati Mukna’an Kingsley Guruyen ni o wa nidi iṣẹlẹ yii.

O soju mi koro kan Daniel Agabi sọ fawọn akọroyin pe Ọgbẹni Guruyen lo kọkọ doju ija kọ akẹgbẹ rẹ.

A ko ribi fìdí ọrọ yi múlẹ ṣugbọn o ni “Mo mọ bi ọrọ yi ṣe waye nitori agbẹjọro ti ẹjẹ bo aṣọ rẹ,Yuwa, akẹgbẹ mi nii ṣe.”

O tẹsiwaju pe lasiko to n sọ atotonu rẹ niwaju adajọ ni agbẹjọro keji saadede fún un ni ẹsẹ ti ẹjẹ dẹ bẹrẹ sí ní da l’ẹnu rẹ”.

Awọn agbẹjọrò tó ń jà

Oríṣun àwòrán, Politicws Nigeria

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni ẹni tí wọn dojú ìjà kọ ko da esi pada ṣugbọn o ke si awọn agbofinro ti wọn si wa gbe akẹgbẹ rẹ janto.

Yato si pe a ri awọn aworan agbẹjọro tí ẹjẹ wa lara aṣọ rẹ, BBC ko ribi fidi ọrọ naa múlẹ ju pé o waye lọjọbo ni ile ẹjọ majisreeti to wa ni Gombe bi ileesẹ iwe iroyin Naijiria, Politics Nigeria ti ṣe sọ.

Kaakiri oju opo ayelujara ni aworan awọn agbẹjọro yii wa ti awọn eeyan si n ṣe èèmọ lórí ohun tó lè dá aduru wahala yi silẹ laarin awọn tó yẹ kí wọn gbofin ro.

Ẹjọ ti a gbọ pe o gbe awọn agbẹjọro mejeeji wa siwaju adajọ ni ṣe pẹlu ẹsẹ ọdaràn ti wọn pe nomba faili naa ni CMCIII/GM/42/2017.

Èyí taa tun ri ka ni pe arakunrin Yuwa ni o n soju ẹni tí wọn fẹsun kan ti akẹgbẹ rẹ Guruyen sí sojú ẹni to gbẹjọ wa.

Awọn tó jẹ akẹgbẹ awọn agbẹjọro mejeeji yi labẹ asia ẹgbẹ awọn agbẹjọro NBA ko tii fesi sí iṣẹlẹ naa.

Amọ iwe iroyin Politics Nigeria sọ pé arakunrin Yuwa ti kọ iwe ẹdun ọkan si ẹgbẹ agbẹjọro to wa ni Gombe pe ki wọn gbe igbese lori iṣẹlẹ ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ