Ǹjẹ́ Bobrisky àti Mompha ń gbée síi fúnra wọn lóòtọ́? Ohun táa mọ̀ nìyí

Bobrisky ati Mompha

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bobrisky

Ilumọọka ọkunrin to wọ aṣọ obinrin, Idris Okuneye, ti ọpọ mọ si Bobrisky, ti sọ pe ko si ohun tọ ahesọ ọrọ to n tan kalẹ lori Instagram pe ọrẹkunrin rẹ ni Ismaila Mustapha, ti iangijẹ rẹ njẹ Mompha.

Koda, Mompha fun ra rẹ naa ti sọ pe ko si ọrọ ifẹ laarin awọn mejeeji eleyii to tako ohun ti oluranlọwọ Bobrisky tẹlẹ ri, Kyme Oye ṣe sọ pe wọn ti fẹ ra ri.

Oye lo sọ pe Mompha ati Bobrisky ti fẹ ra ri nigba ti o n dahun ibeere ẹnikan lori itakun ikansira ẹni Instagram.

Ninu esi rẹ, Mompha faraya, o si sọ pe oun ṣetan lati gbe Oye lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ko ba tọrọ aforijin ni kiakia.

Mompha tun sọ fun Oye pe o gbọdọ yọ ohun to kọ lori ọrọ naa kuro loju opo Instagram rẹ.

Mompha ni ki Oye gbaradi fun oun nitori oun ṣetan lati gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Daddy Freeze lori Instagram lọjọ Abamẹta, Mompha sọ pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe oun ati Bobrisky ti fẹ ra ri.

Mompha fikun ọrọ rẹ pe igba meji pere ni oun ri Bobrisky ri laye oun.

Bakan naa ni Mompha sọ pe oun ti kilọ fun Bobrisky tẹlẹ pe ko ye fi fọto oun soju opo Instagram rẹ mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni awọn obinrin wa nilẹ ti oun ba fẹ ṣe ṣina, Mompha ni ki lo maa sun oun debi pe oun maa ni ajọṣepọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ oun.

Bobrisky naa kuku sọ tẹnu rẹ ninu ifọrọwerọ naa pẹlu Daddy Freeze.

Bobrisky ṣalaye pe ko si ohun to jọ ọrọ ifẹ oun ati Mompha, o ni ko ṣẹlẹ rara.

”Ọrẹ lasan ni emi ati Mompha, ko si ohun to jọ ọrọ ifẹ laarin awa mejeeji.

Igba to kẹyin niyii ti mo maa sọrọ yii pe Mompha kii ṣe ololufẹ mi.

Koda, iyawo Mompha gan an le jẹrio sii pe ọrẹ lasan an ni emi ati Mompha, ko si nkankan laarin wa,” Bobrisky ṣalaye.

Bobrisky ni awọn eeyan mọmọ ran Oye lati sọ ohun to sọ lati da wahala silẹ ni.

O ni ko ye oun ohun ti o mu kawọn eeyan maa gbe ahesọ ọrọ kiri pe oun ati Mompha n fẹ ara wọn.

Bobrisky ni awọn to wa nidi ọrọ yii fẹ da ile Mompha ru ni, ile ti wọn naa si maa daru ni.

Bobrisky ni Oye mọọmọ sọ pe oun n fẹ Mompha, kii ṣe pe o n dahun si ibeere ẹnikan lori ọrọ naa.