Afurasí tó fẹ́ gba N6m ní POS fi mọ́tò tẹ ọ̀gá ọlọ́pàá pa l’Ondo

Aworan afurasi naa ati owo ọwọ rẹ

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ arakunrin kan, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, Godson Tender James, to fi ọkọ pa ọlọpaa kan lopopona Owo si Benin, nilu Ifon, nipinlẹ Ondo.

Ọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 2023 lawọn eeyan bẹrẹ si nii pin fọnran kan lori ẹrọ ayelujara pe awọn ajinigbe lo yinbọn pa ọlọpaa kan nilu Ifọn, nipinlẹ Ondo.

Lẹyin bii wakati mẹrinlelogun ti fanran yi ti n tan kalẹ ni alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Funmilayo Odunlami-Omisanya fi atẹjade sita pe awọn ajinigbe kọ lo pa ọlọpaa to wa ninu fanran naa ati pe awakọ kan lo fi ọkọ gbaa to si salọ.

Odunlami-Omisanya tẹsiwaju pe awakọ to salọ naa ni awọn ọmọ-ogun to wa nilu Sobe nipinlẹ Edo to fara ti ilu Ifon ti mu.

Amọ lakoko ti wọn fi oju ọkunrin naa lede ni olu ileeṣẹ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo lọjọ Aje ọsẹ yi, ẹsun miran ni wọn tun fi kan ọkunrin naa yatọ si ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan-an tẹlẹ.

Ẹsun miran ti wọn fi kan James ni pe o gba owo to din diẹ ni miliọnu marun lọwọ arabirin kan, Mubowale Oshodi, nilu Akure to si salọ.

James fẹ gba miliọnu mẹfa naira ni POS

Ninu ọrọ rẹ pẹlu ikọ iroyin BBC News Yoruba, Arabirin Oshodi wi pe ni ọjọ kọkanlelogun oṣu keje ni James wa ba oun nibi ti oun ti n taja.

Oshodi ṣee lalaye pe “inu ọja Adesida nilu Akure nibi ni mo ti n taja ti mo si tun fun awọn eeyan lowo pẹlu ẹrọ ‘POS’. Idi POS yii ni mo wa ti James ti waa bami pe oun fẹẹ gba miliọnu mẹfa naira.

“Mo sọ fun pe gbogbo owo to wa nilẹ ko ju miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun lọna irinwo naira to si gbaa amọ to fi ayederu ẹri han ọrẹ ẹ mi to yẹ ko san owo ọun sinu asunwọn banki rẹ.

“Lẹyin taa ri pe ko san owo naa ni tootọ la bẹrẹ sii waa kiri ko too di pe a rii ni ile itura kan to farapamọ si.

“Nibi to ti n gbiyanju pe oun yoo san owo naa fun wa lo tun ti sa mọ wa lọwọ to si kọju si ọna to lọ si ilu Owo, leyi to mu ki awọn ọlọpaa o pe gbogbo awọn ikọ to wa loju popo lati da ọkọ rẹ duro to ba de ọdọ wọn.”

Aworan owo ti wọn ba lọwọ rẹ

Alaye ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa

Nigba to n kin ọrọ ti arabirin naa sọ lẹyin, alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, wi pe gbogbo igbiyanju lati da James duro lọna lo jasi pabo bi ko ṣe duro lawọn oriko ayẹwo ti awọn ọlọpaa wa.

Odunlami-Omisanya ni “nibi ti James ti n sa lọ to si kọ lati duro fun awọn ọlọpaa lọna lo ti kọlu ASP Emmanuel Oyewole ni agbegbe Ori Ohin nilu Ifon leyi to mu ẹmi ọlọpaa naa lọ.

“Pẹlu bi o ṣe kọlu ọlọpaa yii, James ko duro rara ko too dipe awọn ologun rii mu nilu Sobe nipinlẹ Edo pẹlu to le diẹ ni miliọnu kan abọ naira.”

Amọ afurasi ọun ni irọ ni gbogbo ẹsun ti wọn ka si oun lọrun toripe oun ko fi ipa tabi ọna eru gba owo lọwọ ẹnikẹni.

James, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọta lati ipinlẹ Delta, ninu ọrọ rẹ wi pe “ohun to da emi ati Oshodi pọ ni pe o paarọ owo to di dọti to wa lọwọọ mi si tuntun. Miliọnu meta le ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira pere si ni.

“Saaju ki n to de ọdọ wọn ni awọn awakọ tirela ti n sọ fun mi pe awọn ajinigbe wa niwaju leyi to mu ki n pinnu lati ma ṣe duro fun wọn.

“Bo tilẹ jẹ pe wọn wọ aṣọ ọlọpaa, mo nigbagbọ pe ọdaran ni wọn lo ṣe mu ki wọn yin ibọn mọ ọkọ mi.”

Odunlami-Omisanya ni afurasi naa yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.