Kazeem Dosunmu, Alfa tó fi owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kọ́ afára fún ìlú rẹ̀

Kazeem Dosunmu, Alfa tó fi owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kọ́ afára fún ìlú rẹ̀

Ọpọ igba ni awa ọmọ eeyan maa n gbẹkẹle ijọba lati ṣe gbogbo ohun ti a nilo ni awujọ wa, koda ko jẹ nnkan ti awa pẹlu le fi ran ara wa tabi awujọ wa lọwọ.

Ọrọ yii ni Ọgbẹni Kazeem Dosunmu ro to fi fun ara rẹ kọ afara ẹlẹsẹ fun awọn olugbe agbegbe Itẹsiwaju Olokuta Oke Odo ni ilu Abẹokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹOgun lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.

Gẹgẹbi ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Alfa Kazeem gẹgẹbi ọpọ eeyan lagbegbe naa ṣe mọ ọ si ṣalaye pe miliọnu mẹwaa Naira ni afara naa na oun to si jẹ wipe apo ara oun loun ti mu gbogbo owo ti oun fi yanju kikọ rẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe lootọ oun ko ni mọto tabi kẹkẹ, sibẹ o kan wu oun lati ọkan wa ni pe bi oun ba le ṣe afara naa yoo tubọ mu irọrun ba lilọ bibọ awọn eeyan agbegbe Itẹsiwaju naa.

‘Mo fi owo ileewe awọn ọmọ mi ra irin fun aṣeyọri iṣẹ yii’

Aworan afara naa

Alfa naa ni ipenija pupọ ni oun dojukọ lojuna ati kọ afara yii ṣugbọn ipinnu ọkan oun lo mu ko pari.

“Owo School awọn ọmọ mi, ti tiṣa ti fi le wọn wale ri, mo ti fi ra irin ti a fi kọ afara yii lori pe ki n saa le ṣe aṣeyọri rẹ.”

O ni lootọ ki ṣe pe oun lowo lọwọ tabi ri jajẹ yatọ si pako, ṣugbọn ilakaka pe ki igbayegbadun gbogbo awọn eeyan to yi oun ka waye lo mu oun ti run bọ akanṣe iṣẹ naa.

Ohun to jẹ iwuri fun lati kọ afara naa

Alfa Kazeem ṣalaye siwaju ssiii pe nigba ti awọn eeyan ṣẹṣẹ n tẹdo si agbegbe naa ni nnkan bi ọgbn ọdun o le diẹ sẹyin, kii rọrun lati mu awọn eeyan wa si agbegbe ọhun nitori ipo ti ọna abawọ agbegbe ọhun wa.

O fi kun un pe gbogbo awọn ti wọn ba ti fẹ mu wọ ibẹ ni wọn maa n sa pada ni ketew ti wọn ba ti ri bi adugbo naa ṣe ri.

O ni oun mọ pe bi eyi ba tẹsiwaju bẹẹ, idagbasoke yoo jina pupọ si agbegbe naa, eyi lo mu ki oun pinnu lọkan oun lati gbe igbesẹ yii.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìwádìí fihàn pé ẹgbẹ́ alákatakítí ẹ̀sìn, ISIS ló wà ní ìdí ìkọlù náà