‘Adeleke kò ní kúrò nípò gómìnà lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal àyàfi…’

Gboyega Oyetola àti Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Gẹ́gẹ́ bí òfin ètò ìdìbò ní Nàìjíríà ṣe fàyè gbà, ẹnikẹ́ni tí èsì ìbò kò bá tẹ́ lọ́rùn ní àǹfàní láti tọ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò lọ láti ṣàgbéyẹ̀wò ètò ìdìbò náà.

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ló máa ń fún ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olùdíje tó bá ń fapájánú ní àǹfàní láti bèèrè ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ lábẹ́ òfin.

Gbogbo nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀ lásìkò ìbò ni ẹni tí ìkéde INEC kò bá tẹ́ lọ́rùn yóò kọ láti fi pe ẹjọ́ níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò èyí tó ní àǹfàní láti ṣe láàárín ọjọ́ mọ́kànlélógún tí INEC bá kéde èsì ìbò.

Tí onítọ̀hún kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọjọ́ yìí, kò ní ní àǹfàní láti pe ẹjọ́ kankan mọ́.

Ọgọ́sàn-án ọjọ́ ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìyẹn Tribunal ní láti fi gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé ẹjọ́ wá síwájú rẹ̀.

Tí Tribunal bá ti wá da ẹjọ́ rẹ̀ tán, ẹnikẹ́ni tàbí ẹgbẹ́ tí ẹjọ́ náà kò bá tẹ́ lọ́rùn ní àǹfàní láàárín ọgọ́ta ọjọ́ tí wọ́n gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ láti fi pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí lábẹ́ òfin ni àyípadà kò lè bá, wọn kì í sún wọn síwájú gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin.

Lẹ́yìn ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, ẹni tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kò bá tún tẹ́ lọ́rùn tún ní àǹfàní láti gba ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílè èdè Nàìjíríà ìyẹn Supreme court lọ láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ rẹ̀.

Ọgọ́sàn-án ọjọ́ náà ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ náà ní láti fi gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Kíni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal ní Osun?

Ìbéèrè tó ti ń gbá ẹnu àwọn ènìyàn láti ìgbà tí Tribunal ti kéde Oyetola gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò Osun ni pé kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Adeleke.

Agbẹjọ́rò kan tó bá BBC News sọ̀rọ̀, Jiti Ogunye ní ìdájọ́ náà kò túmọ̀ sí pé gómìnà àná Gboyega Oyetola yóò kàn dédé gbapò lọ́wọ́ Adeleke bẹ́ẹ̀.

Ogunye ní Adeleke ni yóò máa ṣe ìjọba lọ títí yóò fi pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó bá jẹ́ wí pé ìdájọ́ náà kò tẹ lọ́rùn.

Ó ní Adeleke ni yóò máa ṣe ìjọba lọ títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi máa lọ ní ilé ẹjọ́ tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà kò bá sì ba lára mú yóò wà nípò tí ìlé ẹjọ́ Supreme náà ma fi dájọ́.

Ó fi kun pé tó bá jẹ́ wí pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ kò bá lọ bí Adeleke ṣe fẹ́ ni yóò tó kúrò nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun.

Agbẹjọ́rọ̀ Jiti ní Adeleke ní ọgọ́sàn-án ọjọ́ láti fi pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àti láti lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ àmọ́ tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ tí ọjọ́ náà fi pé, wọ́n máa búra wọlé Oyetola gẹ́gẹ́ bí gómìnà.

Awà lẹ́yìn rẹ bí iké títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi parí nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ – Akeredolu sí Oyetola

Gboyega Oyetola, Rotimi Akeredolu àti Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Collage

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Osun èyí tó kéde Oyetola gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí gómìnà Osun.

Akeredolu nínú àtẹ̀jáde tó fi sójú òpó Twitter rẹ̀ ní pẹ̀lú ìdùnnú àti ayọ̀ ni òun fi gba ìròyìn náà àti pé ìdájọ́ náà túmọ̀ sí mímú ìgbòrò bá ìjọba àwaarawa.

Ó ní kò sí àníàní pé ìdájọ́ náà yóò tún mú ìgbéga bá ìjọba àwaarawa tí yóò spi tún fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí ní ìwúrí láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọba àwaarawa.

Ó fi kun pé ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun ló wá sí ìmúṣẹ.

Nígbà tó ń kí Gboyega Oyetola kú oríire, Akeredolu bá àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun àti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ APC lápapọ̀ yọ̀ lórí ìdájọ́ náà nítorí oríire gbogbo àwọn ni.

Akeredolu tún sọ àrídájú rẹ̀ fún Oyetola pé gbágbá ni òun wà lẹ́yìn rẹ bí iké títí àwọn máa fi dé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ tí òun sì gbàgbọ́ pé dídùn ni ọsàn máa so fún àwọn.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ìdájọ́ yìí yóò tún mú ìgbà ọ̀tun bá àwọn ènìyà ìpínlẹ̀ Osun ni.

Ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun ni ìdájọ́ Tribunal – Fayemi

Gboyega Oyetola, Rotimi Akeredolu àti Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Twitter

Bákan náà ni gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi náà ti kan sáárá sí ìdájọ́ Tribunal.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Fayemi, Ahmad Sajoh fi léde ní ìdájọ́ náà ti fi ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun hàn.

Fayemi tún kan sáárá sí Oyetola bó ṣe tẹ̀lé ìlànà òfin l;ati fi gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ padà.

“Inú mi dùn sí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ̀ ẹ̀hónú ìbò tó sì dámi lójú pé ó jẹ́ ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun.”

“Mo kan sáárá sí gómìnà Oyetola fún bó ṣe lo ìlànà òfin láti fi gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ padà.”

Lẹ́yìn ijó jíjó, Adeleke ko ní àkọsílẹ̀ àṣeyọrí kankan bíi gómìnà l‘Osun – Oyetola

Adegboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Adegboyega Oyetola

Ismail Omipidan, tii se Agbenusọ fun gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ti sọrọ lorukọ gomina tẹlẹ naa, lẹyin idajọ igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo to waye lọjọ Ẹti.

Nigba to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, Omipidan ni ẹsun meji ni Adegboyega Oyetola mú lọ si ile ẹjọ.

O ni lati ibẹrẹ igbẹjọ naa si ni awọn ti ni igbagbọ pe ile ẹjọ yoo da awọn lare.

O ni awọn ẹsun mejeeji naa, to ni nkan se pẹlu iwe ẹri ti Adeleke lo ati bi awọn oludibo se pọ ju awọn to yẹ ki wọn dibo lọ.

Omipidan ni lori awọn ẹsun mejeeji yii si ni awn ti n reti pe ile ẹjọ yoo da awọn lare.

“Testimonial ti Adeleke n gbe kiri lo ni oun gba lọdun 1988, gbogbo wa la si mọ pe lọdun 1988, wọn ko tii da ipinlẹ Osun silẹ.

O ni pẹlu idajọ yii, ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni le jawe olubori mọ, koda to ba tẹsiwaju lati tako igbẹjọ igbimọ olugbẹjọ naa lori awọn ẹsun naa.

Lati igba ti Adeleke ti di gomina, ipaniyan n pọ l‘Osun, ti ijo rẹ si n peleke si – Omipidan

Omipidan ni ọpọ awọn to dibo yan Ademola Adeleke ni wọn ti kabamọ pe awọn dibo yan an.

O ni lati igba ti adeleke ti di Gomina l‘Osun, ni ipaniyan ti pọ, ti ijo Gomina Ademola Adeleke si tun n peleke sii.

O ni pẹlu igbejọ yii aala awọn ọmọ ipinlẹ Osun ti ṣẹ nitori wi pe wọn ti ń reti ipadabo Gomina Oyetola.

O wa fọwọ gbaya pe gbogbo ibi to ba wu ki Adeleke lọ, odo ti wọn ba bọ lọdọ Tribunal, naa ni wọn yoo ba bọ.

Kafayat Oyetola atawọn APC to n jo

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Aya Oyetola atawọn ọmọ ẹgbẹ APC l‘Osun mu orin ati ijo bọnu lẹyin abọ idajọ Tribunal

Yoruba ni inu ẹni kii dun, ka pa a mọra.

Idi ree ti aya gomina ana nipinlẹ Osun, Kafayat Oyetola atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC se fi ijo bẹ lẹyin idajọ igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo gomina ni Osun.

Ile Gomina tẹlẹ naa ni ariwo ayọ ati ijo jijo naa ti sọ lẹyin ti wọn gbọ idajọ lori eto idibo ipinlẹ Osun ti igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo naa gbe kalẹ.

Oyetola ni ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori esi idibo kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo ninu oṣu keje ọdun 2022.

Fọnran aworan lo safihan bi iyawo Oyetola, awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn ololufẹ gomina tẹlẹ naa ṣe n fi ijo ra ẹsẹ, ti wọn si n kọrin idupẹ lọwọ Ọlọrun.