Ààyè ni mo gbé ìyàwó mi délé ìwòsàn àmọ́ wọ́n kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀ tó fi kú – Ọkọ Bolanle Raheem

Aworan

Oríṣun àwòrán, Bolane Raheem

Gbenga Raheem, ọkọ oloogbe Bolanle Raheem to padanu ẹmi rẹ lọjọ keresimesi lọdun 2022, farahan ni ileẹjọ lati sọ bi isẹlẹ naa ṣe sẹlẹ lọjọ naa.

Igba akọkọ ree ti ọkọ oloogbe naa yoo bọ sita lati sọrọ lẹyin ipapoda iyawo, ọpọ igba lo ti kọjalẹ pe oun ko ni sọ ohunkohun lori isẹlẹ naa.

Ọsẹ to kọja ni wọn sin Oloogbe Bolanle Raheem ni agbegbe Lekki nipinlẹ Eko.

Gbenga wa lara awọn ẹlẹri to farahan ni ileẹjọ ati Titilayo, to jẹ aburo obinrin oloogbe naa.

“Mo fun iyawo mi ni Ẹbun Keresimesi lọjọ to ku”

Ọkọ oloogbe ni igba ti wọn ji lowurọ ọjọ keresimesi ni oun gbe ẹbun fun iyawo oun ati awọn ọmọ to wa nile.

O ni awọn lọ si ile jọsin, ti awọn si gba ibẹ lọ gbafẹ, oun, iyawo rẹ, aburo iyawo oun ,awọn ọmọ pẹlu awọn ọmọ aburo iyawo rẹ.

O ni awọn jẹ Pizza ati Ice Cream papọ ni Domino Pizza, ti isẹlẹ naa si waye afara Ajah lasiko ti awọn pada lọ sile

“Nigba ti mo fẹ yi pada ni afara Ajah, mo ri awọn ọlọpaa ni waju, n ko mọ iye wọn, mo n tẹle ọkọ to wa ni iwaju mi, nigba to ṣe suru nibi kan, mo gba ẹgbẹ ọkọ naa lati bọ si iwaju ni ọlọpaa kan ni ki n duro, nigba ti mo gbinyanju lati duro ni mo gbọ oro ibọn, ti iyawo mi si pariwo, mo ri ẹjẹ ni aya rẹ. Mo bọ silẹ kuro ninu ọkọ lati lọ ba.”

O tẹsiwaju pe Titi to jẹ aburo to wa lẹyin oloogbe pẹlu awọn ọmọ, ni o sa jade lẹsẹkẹsẹ lati lọ ba ọlọpaa to yinbọn naa, to si di lasọ mu. O ni ọlọpaa naa tun dunkoko mọ pe oun yoo yinibọn pẹlu.

“Ẹru ba mi lẹyin ti mo ri ẹjẹ laya iyawo mi.”

Lasiko ti ifọrọwerọ naa tẹsiwaju ni ileẹjọ, Ẹlẹrii na ka si olujẹjọ to jẹ ọlọpaa gẹgẹ bi ẹni to yinbọn pa iyawo rẹ.

O salaye pe bi awọn ṣe sare si ọlọpaa, Titi bu lasọ, to si fa wọle sinu ọkọ ti oloogbe naa wa niwaju ọkọ.

“Ile wosan kọ lati tẹwọ gba iyawo mi”

Gbenga sọ fun ileẹjọ pe ni igba to oun gbe oloogbe de ile wosan Epodo, o gbe iyawo rẹ wọle, to si n pe fun iranlọwọ pe wọn ti yinbọn lu iyawo oun.

“Ọkan lara awọn dokita wọn jade lati sọfun mi pe awọn ko ki n ṣe iru isẹ bayi, pe ki gbe ile wosan to wa ni tosi wọn, Doren.

O ni igba ti oun gbe de Ile wosan Doren, o ni dokita bere pe kilo sẹlẹ, ti oun si salaye fun pe ko ran iyawo oun lọwọ.

“Wọn gbe afẹfẹ gaasi jade, wọn gbe si nimu, wọn fi owu si laya nitori ẹjẹ. O fẹ gbadura sugbọn dokita ni ko ma sọrọ.

“Nigba to ya, o ni oun ko le mi mọ. Ko pẹ si igba yẹn ni dokita ni ki a wa ma gbelọ si ile wosan miiran, Grandville ni VGC.

“Mo fi ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe mo ni owo lọwọ, pe ki wọn dola ẹmi iyawo mi.”

“Mo sọ fun dokita pe mo le wa ọkọ pajajawiri sugbọn wọn ko si kọkọrọ”

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni ile wosan ni awọn lilo lati gbe ọkọ pajawiri sugbọn ko si ẹni ti yoo wa ọkọ nilẹ bayi. Ọkọ oloogbe ni oun sọ fun dokita pe oun le wa ọkọ pajawiri naa sugbọn wọn ni direba ti mu kọkọrọ lọ.

O ni oun ko ni ọna miiran ju ki oun lo ọkọ toun lọ nigba ti oun ri pe o ti n rẹ iyawo oun, ti wọn si bẹrẹ si ni ma tẹ ni igba aya rẹ.

O ni oun igbiyanju lati jẹ pe ọkan lara awọn dokita ile wosan ọhun tẹle wọn lọ si ile wosan kẹta sugbọn wọn ni rara.

Ọkọ ọlọpaa pada wa si ile wosan, ti oun ati awọn si gbe iyawo rẹ lọ si ile wosan kẹta. O ni oun ko mọ agbegbe naa dada sugbọn lẹyin ti wọn sina ni ọpọ igba, wọn pada jasi ile wosan Grandville . o ni oun sa jade, ti o si pariwo fun iranlọwọ.

Gbenga ni “ọmọ obinrin kan jade lati wa yẹwo, mo ro pe wọn fẹ gbe wọle ni sugbọn niṣe ni wọn yẹ ifunpa rẹ wo, ti wọn si ni o ti jade lade. N ko le sọ nkankan, awọn olopaa gbe oku iyawo mi si ẹyin ọkọ. Mo n wo oku iyawo mi lọ bi awọn ọlọpaa ṣe n gbe lọ.”

O ni nigba to ya oun pada si ile lati lo wo awọn ọmọ, ti oun si pada si ileeṣẹ ọlọpaa lati lọ kọwe nipa nkan to sẹlẹ.

Nigba ti wọn bere ibeere lọwọ rẹ pe boya ni oun ati aburo iyawo rẹ sọrọ kankan si awọn ọlọpaa nigba ti isẹlẹ naa waye, o ni rara nitori pe awọn ko wi ohunkohun.

Mo lo gbogbo agbara mi lati wọ ọlọpaa lọ si ẹgbẹ ọkọ wa – Aburo Bolanle

Lẹyin ti ọkọ oloogbe wi tẹnu rẹ tan, aburo iyawo, Titilayo Emenam bọ ninu apoti lati sọ nnkan to sẹlẹ.

O sọfun ileẹjọ pe olujẹjọ lo yinbọn lu ẹgbọn rẹ ati pe o tun doju ibọn kọ oun naa. O ni gbogbo agbara oun ni oun lo lati mu ọlọpaa naa, ti oun si wọ pe ko wa wo ohun to ṣe.

“Lakọkọ, mo rope o lo ibọn fi fọ gilaasi ọkọ sugbọn mo gbọ ti ẹgbọn mi sọ pe “Gbenga, ọta ibọn ti wọ aya mi” o ṣo ni igbameji.

O ni igba ti oun sumọ ọlọpaa naa, ọlọpaa naa dunkoko lati yinbọn lu oun naa sugbọn awọn ọkunrin to wa si tosi mi, to ri nnkan to sẹlẹ fun ni igbarasi.

Adajọ Sonaike ti wa sun igbẹjọ si ọjọ kinni ati keji oṣu keji fun itẹsiwaju igbẹjọ naa.