Lónìí ni Cubana Chief Priest yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ – EFCC

Aworan Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, Cubana Chief Priest/Instagram

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti sọ pe awọn yoo fi oju gbajugbaja oniṣowo nni, Pascal Okechukwu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Cubana Chief Priest ba ile-ẹjọ.

Ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Cubana Chief Priest ni pe o wa lara awọn to n ṣe owo naira niṣekuṣe, gẹgẹ bi eyi ti wọn fi kan ọdọmọkunrin to n ṣebi obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ile-ẹjọ giga apapọ ju Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lai fi aye silẹ fun owo itanran rara.

Oni tii ṣe Ọjọru ni ajọ EFCC sọ pe Cubana Chief Priest yoo fi oju ba ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Eko lori bo ṣe n fọn owo ka nita gbangba, eyi ti wọn lo tapa si ofin banki agba orileede yii, iyẹn Central Bank Act of 2007.

Nigba to n fidi iroyin mulẹ, Dele Oyewale to jẹ agbẹnusọ ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Cubana Chief Priest, ti awọn yoo si fi oju rẹ ile-ẹjọ.

“Bẹẹni, Cubana Chief Priest ti wa ni ahamọ wa, a si maa fi oju ba ile-ẹjọ l’Ọjọru, ọsẹ yii.”

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2024 ti a wa yii ni agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo ati awọn agbẹjọro meje miran ti wọn ṣoju alaga EFCC, Ọla Olukayọde fi ẹsun kan Pascal Okechukwu wi pe o na owo naira loju agbo, ti wọn si tun n tẹ ẹ mọlẹ.

Ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2024 ni wọn sọ pe Pascal ṣe owo naira niṣekuṣe ni otẹẹli Eko (Eko Hotel), eyi ti wọn lo tako ofin banki apapọ lori nina owo naira, to si ni ijiya ninu ni abala kọkanlelogun akọkọ.