Àṣírí tú bí ọlọ́pàá Amẹ́ríkà 7, òṣìṣẹ iléèwòsàn 3 ṣe fi tipátipá mú ọkùnrin yìí mọ́lẹ̀ títí tó fi kú

Awọn olugbẹjo orilẹede Amerika ti fi fọ́nrán to ni ṣe pẹlu iku Irvo Otieno ọmọ orilẹede Kenya to fi ilu Amẹrika ṣe ibugbe lede.

Irvo ninu fọ́nrán naa ni awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ ile iwosan awọn alaarun ọpọlọ fi tipatipa muu molẹ titi ẹmi fi bọ lara rẹ.

Isẹlẹ naaa lo waye ni ọjọ kẹfa osu yii, ti awọn mẹwa to jẹbi ẹsun naa si ti foju ba ile ẹjọ fun ẹsun to nii ṣe pẹlu isekupani.

Ninu fọ́nrán ti wọn fi lede, awọn mẹwa lo fi agbara mu Irvo mọlẹ, osiṣẹ ọlọpaa meje ati oṣiṣẹ ile iwosan ọpọlọ mẹta.

Ọjọ Iṣẹgun ni adajọ Ann Cabell Baskervill, fi fọ́nrán isẹlẹ to waye ọhun ni ile iwosan ijọba Petersburg, ni ilu Virginia lede.

Otieno

Oríṣun àwòrán, BEN CRUMB LAW

Otieno ni wọn fi pampẹ ọba mu ni ọjọ kẹta osu yii fun ẹsun ole jija ti wọn si fi si ile itọju awọn alarun ọpọlọ ki o ma baa se ara rẹ leṣe.

Fọ́nrán naa fi bi awọn osiṣẹ ọlọpa ṣe fi tipatipa mu Otieno mọle lẹyin ti wọn ti fi ṣẹkẹṣẹkẹ mu u lọwọ ati ẹsẹ.

Ninu ipade oniroyin ti iya Otieno ṣe, o ni bi awọn alaṣẹ ṣe fi pampẹ ofin gbe awọn ọlọpa to jẹbi yii ati awọn oṣiṣẹ eto ilera mu idunnu ba oun ti o si jẹ ọna to tọ si gbigba idajọ ododo.

AWORAN IRVO OTIENO

Oríṣun àwòrán, BEN CRUMPLAW

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí