Èmi ò fi ìgbà kankan tojúbọ ìdìbò ọdún 2023 – Buhari

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, presidencynigeria

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ pe inu oun dun si ipa ti oun ko ninu eto idibo to waye lorilẹede Naijiria nipa kikọ jalẹ lati ti oju bọ idibo naa.

Aarẹ Buhari ti yoo fi ipo silẹ loṣu karun ọdun 2023 ṣalaye pe itaraṣaṣa ati ipinnu ti awọn eeyan orilẹede Naijiria fihan lati jade dibo yan awọn adari wọn lati jẹ wi pe ẹnikẹni ti wọn gọọgọọ fihan pe eto iṣejọba alagbada lorilẹede Naijiria ti n gbopọn sii.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Malam Garba Shehu ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC pe inu aarẹ dun pe awọn ọmọ Naijiria jade dibo yan ẹni to wu wọn gẹgẹbi adari.

Aarẹ Buhari sọ pe, “Ọpọlọpọ awọn to fidirẹmi ninu idibo yii, paapaajulọ awọn gomina lo n banujẹ, ṣugbọn ti a ba woo daadaa, ohun ti araalu fẹ ni wọn dibo fun eyi to fihan pe wwọn mọ ohun ti wọn fẹ.”

Garba Shehu sọ pe, inu aarẹ Buhari dun pupọ pe gbogbo ọrọ odi asọtẹlẹ ogun ati tẹmbẹlẹkun ti awọn kan sọ pe yoo waye lawọn ipinlẹ kan ko waye, eleyi to ni o mu inu rẹ dun pupọ.

‘Idibo 2023 lo wẹ yan kainkain julọ ni Naijiria’

Aarẹ Buhari pẹlu iyawo rẹ rẹ, Aisha lọ dibo

Oríṣun àwòrán, presidency nigeria

O ṣalaye siwaju sii pe, Ọkan ijọba balẹ lori bi awọn eeyan ṣe jade dibo ati wi pe ko tii si eto idibo to gbounjẹ fẹgbẹ gbawo bọ bi eyi lati igba ti Naijiria ti n ṣeto idibo.

O wa fi kun un pe nnkan to n jẹ idunnu aarẹ bayii ni pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti yan awọn adari ti wọn fẹ, ko si si ẹnikẹni to di wọn lọwọ ṣiṣe bẹẹ.

O ni iṣubu awọn alagbara oloṣelu kan lasiko idibo naa ba aarẹ lọkan jẹ ṣugbọn o ni ko si nnkan ti aarẹ le e ṣe eyi nitori pe ẹtọ awọn araalu lati yan oun ti wọn fẹ ko gbọdọ yingbin.